ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 10/8 ojú ìwé 13-15
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Jí!—2004
Jí!—2004
g04 10/8 ojú ìwé 13-15

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 15. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Kí Jésù Kristi bàa lè mú ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti “má ṣe padà sí àwọn nǹkan tí ń bẹ lẹ́yìn,” ta ló rọ̀ wá pé ká máa rántí? (Lúùkù 17:31, 32)

2. Nínú àkàwé Jésù nípa afúnrúgbìn, kí ló fà á tí irúgbìn tó hù sórí àpáta fi rọ dà nù? (Máàkù 4:5, 6)

3. Kí ni jíjókòó tí Jésù tá a jíǹde á jókòó ní “ọwọ́ ọ̀tún” Jèhófà túmọ̀ sí? (Ìṣe 2:34)

4. Ta ni ara Ṣúáhì kan ṣoṣo tá a mẹ́nu kàn nínú Ìwé Mímọ́? (Jóòbù 8:1)

5. Orúkọ wo ni Ọlọ́run fún Jékọ́bù nígbà tó dẹni nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún? (Jẹ́nẹ́sísì 32:28)

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tó sì ń lépa Dáfídì, kí ló fà á tí Dáfídì ò fi pa Sọ́ọ̀lù nígbà tó láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀? (1 Sámúẹ́lì 26:7-11)

7. Ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jèhófà, àwọn ẹranko wo ló jẹ ẹran ara Jésíbẹ́lì, ẹni burúkú? (2 Àwọn Ọba 9:36)

8. Ibo ni Bíbélì mẹ́nu kàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ́kọ́ dúró nígbà tí wọ́n ń rìn lọ́ síhà Òkun Pupa? (Ẹ́kísódù 12:37)

9. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ṣe sọ, irú ìjọsìn wo ló “mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run . . . wa”? (Jákọ́bù 1:27)

10. Sáà àkókò wo ni Ọlọ́run ṣí payá fún Dáníẹ́lì kó bàa lè mọ ìgbà tí Mèsáyà máa fara hàn àti ìgbà tí a óò ké e kúrò? (Dáníẹ́lì 9:24-27)

11. Kí ni Jésù sọ pé a ó “wàásù” rẹ̀ “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” kí òpin tó dé? (Mátíù 24:14)

12. Kí ni “àwọn iṣẹ́ ti ara” tó lè mú kéèyàn má jogún Ìjọba Ọlọ́run? (Gálátíà 5:19-21)

13. Agbára tí Jèhófà ní wo ló mú kó lè ṣèdájọ́ èèyàn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? (1 Sámúẹ́lì 16:7)

14. Kí Ọlọ́run tó yàn Ámósì gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, iṣẹ́ wo ló ń ṣe? (Ámósì 7:14)

15. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ “kórìíra” àwọn ará ilé wọn? (Lúùkù 14:26)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. “Aya Lọ́ọ̀tì”

2. Nítorí pé kò ní gbòǹgbò ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó lè dúró pẹ́ lábẹ́ oòrùn tí ń mú ganrínganrín

3. Yàtọ̀ sí ti Jèhófà, Jésù ló máa wà ní ipò tó ṣe pàtàkì jù lọ

4. Bílídádì, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta

5. Ísírẹ́lì

6. Jèhófà ti fòróró yan Sọ́ọ̀lù, ìyẹn ló mú kí Dáfídì fi ọ̀rọ̀ náà lé e lọ́wọ́

7. Àwọn ajá

8. Súkótù

9. “Láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé”

10. “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀”

11. “Ìhìn rere ìjọba yìí”

12. “Àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí”

13. “Ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́”

14. Ó ń ṣe iṣẹ́ ‘olùṣọ́ agbo ẹran àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè’

15. Pé kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wọn dín kù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́