“Mi Ò Fẹ́ Gbé E Sílẹ̀ Mọ́”
Ọ̀rọ̀ tí Lenita, tó ka ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! sọ nìyẹn. Nínú lẹ́tà ìmọrírì tó kọ ránṣẹ́, Lenita kígbe pé: “Èyí mà ga o! Ohun tí mò ń sọ yé mi o, àní mi ò fẹ́ gbé e sílẹ̀ mọ́ ni. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kà á, ńṣe ló kọ́kọ́ ń dà bí ìwé ìtàn, títí tí mo sì fi kà á tán, ó kàn ṣáà ń ṣe mí bí ẹni pé èmi àti Dáníẹ́lì jọ gbáyé ni. Ìwé Dáníẹ́lì ò tíì yé mi tó báyìí rí.”
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Síwájú sí i, àgbà ìwé ìtàn ni, ó ṣàlàyé nípa àwọn agbára ayé, àwọn orílẹ̀-èdè tó jagun àtàwọn tí wọ́n bá wọ̀yá ìjà. Ọmọbìnrin wa kékeré tó ń gbélé kàwé ti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, mo sì fẹ́ láti fún un níṣìírí pé kó kà á tán kó sì lò ó láti kọ́ nípa ìtàn.”
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.