Àwọn Àwòrán Ilẹ̀ Tó Ń mú Kí Bíbélì Kíkà Rọrùn
Nígbà tó o bá ń ka ìtàn àwọn èèyàn àti ibi tí wọ́n rìnrìn-àjò lọ nínú Bíbélì, ǹjẹ́ o ti gbìyànjú rí láti fojú inú wo ojú ọ̀nà tí wọ́n gbà àti ibi tí wọ́n lọ? Ìwé àwòrán ilẹ̀ Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, ti wà ní sẹpẹ́ báyìí láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn.
Obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Ireland tó gba ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà ṣàlàyé pé: “Láràárọ̀ tí mo bá ti ń ka Bíbélì, mo máa ń lo ìwé pẹlẹbẹ náà. Ó máa ń dùn mọ́ mi nínú bí mo ṣe máa ń fojú tọpasẹ̀ ibi tí àwọn èèyàn, bí àwọn wòlíì àtàwọn ọba gbà nínú ìwé náà, tí mo sì tún máa ń ronú nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n là kọjá nínú ìrìn àjò wọn, báwọn ibi tí wọ́n lọ ṣe jìnnà tó, àti ọ̀gangan ibi tí wọ́n gbé. Mo máa ń fi àwọn àlàyé kúkurú tèmi kún àwọn àwòrán ilẹ̀ náà bí mo ṣe ń ka Bíbélì lọ. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni mo ṣì ń kà lọ́wọ́ ṣùgbọ́n ńṣe ló ń ṣe mí bíi kí n ti kà á dé Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì.”
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé aláwọ̀ mèremère olójú ewé 36 tí ó ní àkòrí náà, Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sojú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́ mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Àfonífojì olójú ọ̀gbàrá àtàwòrán ẹ̀yìn ìwé pẹlẹbẹ: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.