Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July 8, 2005
Bó O Ṣe Lè Rí Iṣẹ́ Tí Iṣẹ́ Náà Ò sì Ní Bọ́ Lọ́wọ́ Rẹ
Lóde òní táwọn tó ń wáṣẹ́ ti pọ̀ bí rẹ́rẹ yìí, ọ̀rọ̀ àìníṣẹ́lọ́wọ́ ti dogun. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tí wàá fi ríṣẹ́, tí iṣẹ́ ọ̀hún ò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ?
4 Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́
10 Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Iṣẹ́ Ò Fi Ní Bọ́ Mọ́ Ẹ Lọ́wọ́
15 Ṣíṣàfọwọ́rá Ṣé Eré Ọwọ́ Ni Àbí Ìwà Ọ̀daràn?
16 Kí Ló Ń máwọn Èèyàn Ṣàfọwọ́rá?
18 Ta Ló Ń forí Fá Àtúbọ̀tán Ṣíṣàfọwọ́rá?
21 Bá A Ṣe Lè Fòpin Sí Ṣíṣàfọwọ́rá
23 “A Kì Í Sọ̀rọ̀ Àlùfààṣá Lédè Tiwa”
26 Mo Pinnu Pé Mo Gbọ́dọ̀ Bá Ohun Tí Mò Ń Lé
28 Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbe Omi Òjò Látijọ́ Àti Lóde Òní
32 Wá Kọ́ nípa ohun tí Bíbélì Sọ
Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀dọ́bìnrin Kan Bá Dẹnu Ìfẹ́ Kọ Mí? 12
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu, ó lè dùn mọ́ ẹ nínú, tàbí kó tì ẹ́ lójú tó o bá gbọ́ tẹ́nì kan sọ irú ẹ̀ sí ọ, àmọ́ kí lo máa ṣe?
Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Amágẹ́dọ́nì? 24
Oríṣiríṣi èrò òdì làwọn èèyàn ní nípa Amágẹ́dọ́nì. Ojú wo ló yẹ ká fi wo ohun tí Bíbélì sọ nípa Amágẹ́dọ́nì?