Ó Fẹ́ràn Rẹ̀ Ju Ohun Ìṣeré Èyíkéyìí Lọ
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe káwọn ọmọdé fẹ́ràn ìwé ju ohun ìṣeré lọ? Bẹ́ẹ̀ ni, báwọn òbí bá tètè fìwé kíkà kọ́ wọn láti kékeré. Látìgbà tí Mebrahtu àtìyàwó ẹ̀ Angela tí wọ́n ń gbé ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti gbọ́mọ wọn obìnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wálé láti ọsibítù ni wọ́n ti ń kàwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà sí i létí.
Àwọn òbí náà kọ̀wé sí ọ́fíìsì wa pé, ìyẹn sì ti mú “kó fẹ́ràn ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Kò sì tíì ju ọmọ ọdún kan lọ tó ti ń fẹnu ara ẹ̀ sọ fún wa pé ká máa ka ìwé Jésù sóun létí, torí bó ṣe ń pe ìwé náà nìyẹn. Ọmọ wa, Juliana, ti pọ́mọ ọdún mẹ́ta báyìí, ojoojúmọ́ lára ẹ̀ sì máa ń wà lọ́nà láti tẹ́tí sí ìwé alárinrin tá a máa ń kà fún un. Tẹnu kọ́, ó fẹ́ràn ìwé náà ju ohun ìṣeré èyíkéyìí lọ. Àwòrán àtàwọn àpèjúwe tó wà nínú ẹ̀ gan-an tó ohun tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́tọ̀. Àwa òbí ẹ̀ náà sì rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ níbẹ̀.”
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan lára ìwé olójú ewé 256, tó ní àwòrán rírẹwà tó sì fẹ̀ tó ìwé ìròyìn yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.