Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
◼ ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí tó ti bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́jọ́ kẹtàlélọ́gbọ̀n sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù May la máa ṣe ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé. Àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjìlá ló pésẹ̀ sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lé igba [3,200] irú àwọn àpéjọ àgbègbè bẹ́ẹ̀ tá a ṣe lọ́dún 2007!
Lọ́pọ̀ ibi tá a ti máa ṣe irú àwọn àpéjọ àgbègbè yìí lọ́dún yìí, orin la fi máa bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní déédé aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú láàárọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Inú ìwé Jòhánù 16:13 la ti mu ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Friday, ìyẹn ni: “Ẹ̀mí . . . Yóò Ṣamọ̀nà Yín Sínú Òtítọ́ Gbogbo.” Lára àwọn àsọyé tá a máa kọ́kọ́ gbọ́ ni “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?” àti “A Rọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ Lára Ìṣẹ̀dá!” Apá mẹ́ta tí àpínsọ àsọyé tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Olóòótọ́” máa pín sí ni, “Nígbà Ayé Mósè,” “Nígbà Ayé Àwọn Onídàájọ́,” àti “Ní Ọ̀rúndún Kìíní.” Lájorí àsọyé tá a máa fi kádìí ìpàdé àárọ̀ ni, “Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Nínú Mímú Ète Jèhófà Ṣẹ.”
Lọ́sàn-án Friday, àsọyé tá a máa kọ́kọ́ gbọ́ ni “Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ Nípa Ẹ̀mí Mímọ́,” lẹ́yìn ìyẹn la máa wá gbọ́ àwọn àsọyé tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ẹ̀mí Ń Wá Inú . . . Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” àti “Ẹ Di Olùgbọ́ àti Olùṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Àwọn apá tí àpínsọ àsọyé náà, “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Yín!” máa pín sí ni, “Níléèwé,” “Níbi Iṣẹ́,” “Nínú Ìdílé,” “Nínú Ìjọ,” “Nígbà Tẹ́ Ẹ Bá Ń Gbafẹ́,” àti “Nígbà Tẹ́ Ẹ Bá Dá Wà.” Kókó pàtàkì tá a máa fi kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday ni, “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Àjọṣe Yín Pẹ̀lú Jèhófà Bà Jẹ́!,” àsọyé yìí sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Saturday ni, ‘Fífúnrúgbìn Pẹ̀lú Níní Ẹ̀mí Lọ́kàn,’ a gbé e ka ìwé Gálátíà 6:8. Lára àwọn àsọyé tá a máa gbọ́ láàárọ̀ Saturday ni àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta náà, “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa.” Àsọyé tó máa dá lórí ìrìbọmi la máa fi mú ìpàdé àárọ̀ wá síparí, lẹ́yìn ìyẹn sì làwọn tó bá tóótun máa ṣèrìbọmi.
Àsọyé tá a máa kọ́kọ́ gbọ́ lọ́sàn-án Saturday ni, “‘Ẹ̀mí Mímọ́ Ló Darí’ Àwọn Tó Kọ Bíbélì,” àpínsọ àsọyé alápá márùn-ún sì máa wá tẹ̀ lé e lábẹ́ àkòrí tó sọ pé “Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Fún Wa Lágbára” “Ká Lè Kojú Ìdẹwò,” “Ká Lè Fara Da Àárẹ̀ àti Ìrẹ̀wẹ̀sì,” “Ká Lè Fara Da Inúnibíni,” “Ká Lè Dènà Ẹ̀mí-Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe,” àti “Ká Lè Fara Da Ìpọ́njú.” Kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tá a máa gbọ́ kẹ́yìn lọ́jọ́ náà ni, ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’
Ẹṣin ọ̀rọ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday tó ní “Ẹ Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí” la mú látinú ìwé Gálátíà 5:16. Àsọyé alápá mẹ́sàn-án náà, “Máa Fi ‘Èso Ti Ẹ̀mí’ Ṣèwà Hù” máa jíròrò apá kọ̀ọ̀kan tí èso ti ẹ̀mí pín sí, bó ti wà nínú ìwé Gálátíà 5:22, 23. Àsọyé fún gbogbo ènìyàn tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Kórè Ìbùkún Yanturu Nípasẹ̀ Ọba tí Jèhófà Ń Fẹ̀mí Rẹ̀ Darí!” la máa fi kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ Sunday. Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tá a máa gbádùn lọ́sàn-án Sunday ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Ẹ Má Ṣe Fi ‘Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ Ní Lákọ̀ọ́kọ́’ Sílẹ̀,” nínú èyí táwọn òṣèré ti máa múra bí àwọn ará ìgbàanì. Ó máa dá lórí àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ àti ìwà tó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni kan hù lọ́wọ́ ìparí ọ̀rúndún kìíní. A máa kádìí àpéjọ àgbègbè náà pẹ̀lú àsọyé náà, “Máa Fi Tọkàntọkàn Sìn Nínú Ètò Tí Jèhófà Ń Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Darí.”
Máa gbára dì báyìí kó o lè wà níbẹ̀. Bó o bá fẹ́ mọ èyí tó sún mọ ẹ jù lọ nínú àwọn ibi tí àpéjọ àgbègbè náà ti máa wáyé, o lè kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.