Bí Wọ́n Ṣe Ń dàgbà
“Nígbà tá a wà lọ́mọdé, a gbádùn kíka Ìwé Ìtàn Bíbélì. Ní báyìí a ti ní ọmọ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joshua. Ìwé yìí wúlò gan-an ni, a sì máa ń fi kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Bí Joshua ṣe kéré tó yìí, àwọn tó dá mọ̀ lára àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn tí àwòrán wọn wà nínú ìwé náà tó márùndínlógójì, ó sì mọ orúkọ wọn. Orúkọ wọn ti di ara ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ.”—Timothy àti Ann.
“Ọmọkùnrin mi tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún fẹ́ràn kó máa ṣí ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, ó sì ti mọ ọ̀pọ̀ lára àwọn àwòrán tó wà nínu rẹ̀. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti fèrò wérò pẹ̀lú rẹ̀ nípa bó ṣe lè borí ìṣòro níléèwé àti níbòmíì. Ìwé yìí dáa gan-an ni!”—Jennifer.
“Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, sọ̀rọ̀ nípa gbogbo nǹkan tó lè máa jẹ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mi. Ìwé yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní àwọn àfojúsùn, láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nípa bí mo ṣe lè yan ẹni tí màá fẹ́, ó sì ti jẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i. Mo dábàá pé kí gbogbo èèyàn ka ìwé yìí, àtàgbà àtọmọdé.”—Courtney.
□ Ìwé Ìtàn Bíbélì
□ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
□ Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí. Sọ èyí tó o bá fẹ́. Kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó bá sún mọ́ ẹ jùlọ lára àwọn tá a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí. Kọ èdè tó o fẹ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.