ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/12 ojú ìwé 32
  • “Àwọn Ohun Àtijọ́ . . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Àwọn Ohun Àtijọ́ . . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà”
  • Jí!—2012
Jí!—2012
g 7/12 ojú ìwé 32

“Àwọn Ohun Àtijọ́ . . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà”

Ẹlẹ́dàá wa ti fi ohun tó máa ṣe láìpẹ́ hàn wá. Ó sọ pé:

“Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—AÍSÁYÀ 65:17.

Àwọn nǹkan wo ni “àwọn ohun àtijọ́” tí “kì yóò wá sí ọkàn-àyà”? Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà ìrẹ́jẹ, àìsàn, ìyà àtàwọn wàhálà míì tó ń dààmú aráyé ni àwọn ohun àtijọ́ yìí. Báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe máa dópin? Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí “ọ̀run tuntun” àti “ayé tuntun” tí Ọlọ́run ṣèlérí bá dé.”

A máa gbọ́ àlàyé lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí àti ìtumọ̀ wọn nínú àsọyé fún gbogbo èèyàn náà, “Àwọn Ohun Àtijọ́. . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà.” Àpéjọ Àgbègbè tá a pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní, “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò la ti máa gbọ́ àsọyé yìí, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní September 2012, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Tìfẹ́tìfẹ́ la pè ọ́ pé kó o lọ síbi tó sún mọ́ ẹ jù lọ nínú àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí. Tó o bá fẹ́ mọ ibi tó sún mọ́ ẹ jù lọ, béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. A kọ àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí kárí ayé sórí ìkànnì www.jw.org lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́