Bó o ṣe lè jàǹfààní látinú ìwé yìí:
Ìwé yìí máa jẹ́ kó o lè fojú ara rẹ rí ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kọ sí ìparí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan á jẹ́ kó o mọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn nínú Bíbélì rẹ sí àwọn ìbéèrè tá a kọ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀.
Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, ronú lórí bí wọ́n ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn gan-an láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà ń sọ.—Ka Lúùkù 24:32, 45.
Àkíyèsí: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ gbogbo ìwé tá a tọ́ka sí nínú ìwé yìí.