ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 34 ojú ìwé 84-ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 2
  • Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Idà Jèhófà Àti Ti Gídíónì!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Gídíónì Àti Ọ̀ọ́dúnrún Ọkùnrin Rẹ̀
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Gídíónì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Jèhófà—Ọ̀rẹ́ Wa Tímọ́tímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 34 ojú ìwé 84-ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 2
Gídíónì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ fọn ìwo, wọ́n fọ́ ìkòkò mọ́lẹ̀, wọ́n ń fi iná, wọ́n sì ń pariwo

Ẹ̀KỌ́ 34

Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì ń bọ òrìṣà. Fún ọdún méje gbáko, àwọn ará Mídíánì máa ń jí ẹran ọ̀sìn wọn, wọ́n sì ń ba irè oko wọn jẹ́. Inú ihò àpáta àti orí òkè làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sá pa mọ́ sí káwọn ará Mídíánì má bàa rí wọn. Wọ́n wá gbàdúrà pé kí Jèhófà gba àwọn. Torí náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Gídíónì. Áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Jèhófà ti yàn ẹ́ láti jẹ́ akínkanjú jagunjagun.’ Gídíónì wá béèrè pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀? Èmi tí mi ò já mọ́ nǹkan kan.’

Báwo ni Gídíónì ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti yan òun? Ó mú òwú kan sílẹ̀, ó sì sọ fún Jèhófà pé: ‘Láàárọ̀ ọ̀la, tí ìrì bá sẹ̀ sí òwú yìí nìkan tílẹ̀ sì gbẹ, màá mọ̀ pé lóòótọ́ lo fẹ́ kí n gba Ísírẹ́lì là.’ Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ìrì sẹ̀ sí òwú yẹn nìkan, ilẹ̀ sì gbẹ! Àmọ́ Gídíónì tún sọ pé tó bá di ọjọ́ kejì, kí òwú yẹn nìkan gbẹ, àmọ́ kílẹ̀ tutù. Nígbà tíyẹn náà ṣẹlẹ̀, ó dá Gídíónì lójú pé Jèhófà ti yan òun lóòótọ́. Ni Gídíónì bá kó àwọn ọmọ ogun jọ láti bá àwọn ará Mídíánì jà.

Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Màá jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì pọ̀, ẹ lè rò pé ẹ̀yin fúnra yín lẹ ṣẹ́gun. Sọ fun wọn pé kí ẹnikẹ́ni tẹ́rù ń bà pa dà sílé.’ Torí náà, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ọmọ ogun náà pa dà sílé, ó wá ku ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) péré. Jèhófà tún sọ pé: ‘Àwọn ọmọ ogun yìí ṣì pọ̀. Kó wọn lọ sétí odò, kó o sì sọ fún wọn pé kí wọ́n mu omi. Kìkì àwọn tó ń fojú ẹ̀gbẹ́ kan ṣọ́ àwọn ọ̀tá nígbà tí wọ́n ń mu omi ni kó o yàn.’ Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọmọ ogún péré ló ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà wá ṣèlérí pé ìwọ̀nba àwọn ọmọ ogun yẹn ló máa ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Mídíánì tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje (135,000).

Lóru ọjọ́ yẹn, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Ó ti tó àkókò báyìí láti lọ bá àwọn ọmọ ogún Mídíánì jà!’ Gídíónì fún àwọn ọmọ ogún ẹ̀ ní ìwo àti ìkòkò ńlá kan tí iná wà nínú ẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa wò mí, kẹ́ ẹ sì ṣe bí mo ti ṣe.’ Gídíónì fọn ìwo ọwọ́ ẹ̀, ó fọ́ ìkòkò náà mọ́lẹ̀, ó fi ìná náà sọ́tùn-ún sósì, ó sì pariwo pé: ‘Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!’ Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ogun Mídíánì, wọ́n wá ń sá káàkiri. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ara wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá.

Àwọn ọmọ ogun Mídíánì tẹ́rù ń bà

“Kí agbára tó kọjá ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kó má sì jẹ́ látọ̀dọ̀ wa.”​—2 Kọ́ríńtì 4:7

Ìbéèrè: Kí ni Jèhófà ṣe tí Gídíónì fi mọ̀ pé ó ti yan òun? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) péré làwọn ọmọ ogun Gídíónì?

Àwọn Onídàájọ́ 6:1-16; 6:36–7:25; 8:28

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́