ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 52 ojú ìwé 126-ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 1
  • Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • “Gbé Ọmọkùnrin Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 52 ojú ìwé 126-ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 1
Àwọn ọmọ ogun Síríà yí Èlíṣà àti ìránṣẹ́ ẹ̀ ká

Ẹ̀KỌ́ 52

Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà

Bẹni-Hádádì ọba Síríà ti ń gbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́, ohun tó ń kó ọba Ísírẹ́lì yọ ni pé gbogbo ìgbà ni wòlíì Èlíṣà máa ń kọ́ ọ ní ohun tó máa ṣe kí ọba Síríà má bàa borí ẹ̀. Torí náà, Bẹni-Hádádì wá ṣètò bí wọ́n á ṣe jí wòlíì Èlíṣà gbé. Ó gbọ́ pé Èlíṣà wà nílùú kan tó ń jẹ́ Dótánì, ló bá rán àwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú un wá.

Ilẹ̀ ti ṣú nígbà táwọn ọmọ ogun Síríà dé Dótánì. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì tí ìránṣẹ́ Èlíṣà bọ́ síta, ó rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ti yí ìlú náà ká. Ẹ̀rù bà á, ló bá kígbe pé: ‘Èlíṣà, kí la máa ṣe báyìí?’ Èlíṣà sọ fún un pé: ‘Àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn lọ.’ Nígbà náà ni Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ Èlíṣà, ó wá rí i pé gbogbo òkè ńlá tó yí wọn ká kún fún àwọn ẹṣin àtàwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná.

Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ rí àwọn ọmọ ogun áńgẹ́lì tó yí wọn ká

Báwọn ọmọ ogun Síríà ṣe fẹ́ wá mú Èlíṣà, Èlíṣà gbàdúrà, ó ní: ‘Jèhófà jọ̀ọ́, fọ́ ojú wọn.’ Lójijì, àwọn ọmọ ogun náà ò mọ ibi tí wọ́n wà mọ́. Wọ́n la ojú wọn sílẹ̀, àmọ́ wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mọ́. Èlíṣà wá lọ bá wọn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ ti ṣìnà, ibí kọ́ ló yẹ kẹ́ ẹ wá. Ẹ tẹ̀ lé mi, màá mú yín lọ sọ́dọ̀ ẹni tẹ́ ẹ̀ ń wá.’ Wọ́n wá tẹ̀ lé Èlíṣà títí wọ́n fi dé Samáríà, níbi tí ọba Ísírẹ́lì ń gbé.

Ìgbà yẹn lojú wọn tó là. Àmọ́ kò sóhun tí wọ́n lè ṣe mọ́. Ọba Ísírẹ́lì wá béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà pé: ‘Ṣé kí n pa wọ́n?’ Ṣé Èlíṣà wá lo àkókò yìí láti gbẹ̀san lára àwọn ọmọ ogun tó fẹ́ wá jí i gbé? Rárá kò ṣe bẹ́ẹ̀. Èlíṣà sọ pé: ‘Má pa wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, fún wọn lóúnjẹ, kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì máa lọ.’ Ọba wá se oúnjẹ rẹpẹtẹ fún wọn, lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán, ó ní kí wọ́n máa lọ sílé wọn.

Àwọn ọmọ ogun Síríà jẹun ní Samáríà

“Ohun tó dá wa lójú nípa rẹ̀ ni pé, tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”​—1 Jòhánù 5:14

Ìbéèrè: Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Èlíṣà àti ìránṣẹ́ ẹ̀? Ṣé o rò pé Jèhófà lè dáàbò bo ìwọ náà?

2 Àwọn Ọba 6:8-24

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́