ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 59 ojú ìwé 142-ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 5
  • Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọmọkùnrin Mẹ́rin Ní Bábílónì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • A Dàn Wọn Wò—Ṣùgbọ́n Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Jèhófà!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Eré
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 59 ojú ìwé 142-ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 5
Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà kọ̀ láti jẹ oúnjẹ ọba

Ẹ̀KỌ́ 59

Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà

Nígbà tí Nebukadinésárì mú àwọn ìjòyè Júdà lẹ́rú lọ sí Bábílónì, ó sọ pé kí òṣìṣẹ́ ààfin kan tó ń jẹ́ Áṣípénásì máa bójú tó wọn. Nebukadinésárì wá sọ fún Áṣípénásì pé kó wá àwọn ọ̀dọ́kùnrin tára wọn le, tí wọ́n sì gbọ́n dáadáa lára wọn. Kí wọ́n kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́ta. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí á jẹ́ kí wọ́n lè dé ipò pàtàkì nínú ìjọba Bábílónì. Wọ́n kọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà ní ìwé kíkà, ìwé kíkọ àti bí wọ́n ṣe lè sọ èdè Ákádì ti ilẹ̀ Bábílónì. Oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ààfin ni wọ́n retí pé káwọn ọ̀dọ́kùnrin náà máa jẹ. Orúkọ mẹ́rin lára wọn ni Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. Àmọ́ Áṣípénásì fún wọn ní orúkọ Bábílónì, ìyẹn Bẹtiṣásárì, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Ṣé ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà máa mú kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀?

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin yìí pinnu pé àwọn máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Wọ́n tún mọ̀ pé kò yẹ káwọn jẹ oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ láàfin torí pé Òfin Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ irú àwọn oúnjẹ kan tí wọ́n ń jẹ níbẹ̀. Torí náà, wọ́n sọ fún Áṣípénásì pé: ‘Jọ̀ọ́ má ṣe fún wa ní oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ààfin.’ Áṣípénásì dáhùn pé: ‘Tẹ́ ò bá jẹun, ńṣe lẹ máa rù, tí ọba bá sì rí i, ó máa pa mí!’

Dáníẹ́lì wá sọ pé kó jẹ́ kí àwọn dá ọgbọ́n kan. Ó ní: ‘Máa fún wa ní ẹ̀fọ́ àti omi fún ọjọ́ mẹ́wàá. Kó o wá wò ó bóyá àwọn tó ń jẹ oúnjẹ ọba máa dáa jù wá lọ.’ Áṣípénásì gbà pẹ̀lú wọn.

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dáa ju àwọn ọmọkùnrin tó kù lọ. Inú Jèhófà dùn gan-an torí pé wọ́n ṣègbọràn sí i. Ó sì fún Dáníẹ́lì ní ọgbọ́n tó lè fi lóye ìtumọ̀ àlá àti ìran.

Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn parí, Áṣípénásì kó gbogbo àwọn ọmọkùnrin náà wá síwájú Nebukadinésárì. Nígbà tí ọba bá wọn sọ̀rọ̀, ó rí i pé Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà gbọ́n ju àwọn ọmọkùnrin yòókù lọ. Ó wá yan àwọn mẹ́rin yìí láti máa ṣiṣẹ́ láàfin ẹ̀. Ọba sì máa ń gba ìmọ̀ràn lórí àwọn nǹkan pàtàkì lọ́dọ̀ wọn. Kódà, Jèhófà tún mú kí wọ́n gbọ́n ju àwọn ọlọ́gbọ́n àtàwọn pidánpidán tó wà láàfin ọba lọ.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìlú míì ni wọ́n wà, Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà kò gbàgbé pé èèyàn Jèhófà ni àwọn. Ṣé ìwọ náà á máa rántí Jèhófà kódà nígbà táwọn òbí ẹ kò bá sí pẹ̀lú ẹ?

“Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá. Àmọ́, kí o jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.”​—1 Tímótì 4:12

Ìbéèrè: Kí nìdí tí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ṣègbọràn sí Jèhófà? Báwo ni Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?

Dáníẹ́lì 1:1-21

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́