ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 66 ojú ìwé 156
  • Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́sírà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ǹjẹ́ Bó O Ṣe Ń Kọ́ni Múná Dóko?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 66 ojú ìwé 156
Ẹ́sírà ń yin Jèhófà ní ojúde ìlú, àwọn èèyàn náà sì ń nawọ́ sókè láti fi hàn pé àwọn gbà pẹ̀lú ẹ̀

Ẹ̀KỌ́ 66

Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run

Ó ti tó àádọ́rin (70) ọdún tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n àwọn kan ṣì ń gbé àwọn ilẹ̀ tó wà káàkiri tí Ọba Páṣíà ń ṣàkóso lé lórí. Ọ̀kan lára wọn ni àlùfáà kan tó ń jẹ́ Ẹ́sírà, tó máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Jèhófà. Ẹ́sírà gbọ́ pé àwọn tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù ò pa Òfin Ọlọ́run mọ́, ó sì fẹ́ lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọba ilẹ̀ Páṣíà tó ń jẹ́ Atasásítà sọ fún un pé: ‘Ọlọ́run ló fún ẹ lọ́gbọ́n kó o lè kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin ẹ̀. Máa lọ, kó o sì mú ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá ẹ lọ dání.’ Ẹ́sírà lọ bá àwọn tó fẹ́ láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bo àwọn lójú ọ̀nà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, wọ́n dé Jerúsálẹ́mù. Àwọn olórí tó wà pẹ̀lú Ẹ́sírà wá sọ fún un pé: ‘Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n lọ fẹ́ àwọn obìnrin tó ń bọ̀rìṣà.’ Kí ni Ẹ́sírà wá ṣe? Níwájú àwọn èèyàn náà, Ẹ́sírà kúnlẹ̀, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan rere lo ti ṣe fún wa, àmọ́ a ti ṣẹ̀ ọ́.’ Àwọn èèyàn náà ti ronú pìwà dà, àmọ́ wọ́n ṣì ń ṣe ohun tí ò dáa. Ẹ́sírà yan àwọn àgbà ọkùnrin àtàwọn onídàájọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Láàárín oṣù mẹ́ta tó tẹ̀ lé e, gbogbo àwọn tí kò sin Jèhófà ni wọ́n lé kúrò.

Ọdún méjìlá kọjá. Láàárín àkókò yẹn, wọ́n tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. Lẹ́yìn náà, Ẹ́sírà kó àwọn èèyàn náà jọ síta gbangba láti ka Òfin Ọlọ́run fún wọn. Nígbà tí Ẹ́sírà ṣí ìwé náà, àwọn èèyàn náà dìde. Ó yin Jèhófà, àwọn èèyàn náà sì gbé ọwọ́ wọn sókè láti fi hàn pé àwọn fara mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, Ẹ́sírà ka òfin yìí síta, ó sì ń ṣàlàyé ẹ̀. Gbogbo wọn ń fetí sílẹ̀, wọ́n gbà pé àwọn ti ṣẹ Jèhófà, wọ́n sì ń sunkún. Lọ́jọ́ kejì, Ẹ́sírà tún ka Òfin náà fún wọn. Wọ́n rí i pé àsìkò tó yẹ káwọn ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà ti sún mọ́. Lójú ẹsẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ mọ́ fún àjọyọ̀ náà.

Ní gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àjọyọ̀ náà, wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ń yọ̀ torí irè oko wọn dáa. Kò tíì sírú Àjọyọ̀ Àtíbàbà bí èyí látìgbà ayé Jóṣúà. Lẹ́yìn àjọyọ̀ náà, àwọn èèyàn náà kóra jọ, wọ́n sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, o mú wa kúrò lóko ẹrú, o pèsè fún wa nígbà tá a wà ní aginjù, o sì fún wa nílẹ̀ dáadáa yìí. Síbẹ̀, léraléra là ń ṣẹ̀ ọ́. O rán àwọn wòlíì sí wa láti kìlọ̀ fún wa, àmọ́ a ò fetí sílẹ̀. Síbẹ̀, ò ń ṣe sùúrù fún wa. O mú ìlérí tó o ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ. Àwa náà ń ṣèlérí báyìí pé a máa ṣe ohun tó o fẹ́.’ Wọ́n kọ ìlérí wọn sílẹ̀, àwọn olórí, àwọn ọmọ Léfì àtàwọn àlùfáà sì fọwọ́ sí i.

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:28

Ìbéèrè: Kí ni Ẹ́sírà kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kóra jọ ní Jerúsálẹ́mù? Kí làwọn èèyàn náà ṣèlérí pé àwọn máa ṣe?

Ẹ́sírà 7:1-28; 8:21-23, 31, 32; 9:1–10:19; Nehemáyà 8:1-18; 9:1-38

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́