Ìyàsímímọ́
Kí ló yẹ kó mú ká fẹ́ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run?
Tún wo Ẹk 20:5
Tá a bá fẹ́ sin Ọlọ́run, èrò wo ló yẹ ká ní nípa Bíbélì?
Ètò wo ni Ọlọ́run ti ṣe fún wa ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀?
Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe tó máa fi hàn pé a ti ronú pìwà dà lóòótọ́?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Lk 19:1-10—Sákéù tó jẹ́ olórí àwọn agbowó orí máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, àmọ́ nígbà tó ronú pìwà dà, ó dá owó àwọn tó ti rẹ́ jẹ pa dà fún wọn
1Ti 1:12-16—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ìwà burúkú lòun ń hù tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tóun yí pa dà, Ọlọ́run àti Jésù Kristi ṣàánú òun, wọ́n sì dárí ji òun
Lẹ́yìn tá a bá ti jáwọ́ nínú ìwà burúkú, kí ló tún yẹ ká máa ṣe?
Àwọn ìwà wo ló yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa?
1Kọ 6:9-11; Kol 3:5-9; 1Pe 1:14, 15; 4:3, 4
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Kọ 5:1-13—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé kí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì yọ ọkùnrin kan tó jẹ́ oníṣekúṣe kúrò nínú ìjọ
2Ti 2:16-19—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì pé kó má ṣe tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀yìndà, èyí tó máa ń tàn kálẹ̀ bí egbò tó ti kẹ̀
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jo 6:10-15—Lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, àwọn èèyàn fẹ́ fi jọba, àmọ́ Jésù ò gbà
Jo 18:33-36—Jésù sọ pé ìjọba òun kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ètò ìṣèlú ayé yìí
Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè sin Ọlọ́run?
Tún wo Iṣe 20:28; Ef 5:18
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Iṣe 15:28, 29—Ẹ̀mí mímọ́ ló ran ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ tí wọ́n fi ṣe ìpinnu tó dáa nípa ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́
Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi nínú ìjọsìn wa?
Kí nìdí táwọn Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́ fi gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi?
Mt 28:19, 20; Iṣe 2:40, 41; 8:12; 1Pe 3:21
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 3:13-17—Jésù ṣèrìbọmi láti fi hàn pé òun dé láti ṣe ìfẹ́ Bàbá òun
Iṣe 8:26-39—Lẹ́yìn tí ọkùnrin ará Etiópíà kan tó ti ń sin Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jésù Kristi, ó sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi