‘Awọn Ọmọde Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ Ṣáá Ni’
Araadọta ọkẹ awọn idile ti gbadun Iwe Itan Bibeli Mi. Awọn 116 akọsilẹ Bibeli inu rẹ̀ fun onkawe ní èrò kan nipa ohun tí Bibeli ńsọ lapapọ. Ní ibẹrẹ ọdun 1987 ẹnikan lati Iwọ-Oorun Australia ṣapejuwe bí iwe naa ti gbéṣẹ́ tó, ní ṣiṣalaye pe:
“Iṣẹ́ mi jẹ iṣẹ olukọ tí mo sì ńwá ọ̀nà lati ru awọn ọmọde labẹ itọju mi lọ́kàn sókè lati ya gbogbo iṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ wọn sọ́tọ̀ patapata fun Ọlọrun ati Jesu, gẹgẹ bi emi ti ńṣe ninu iṣẹ́ mi fun awọn ọmọde naa. Mo ti sọ ọ di ojúṣe mi lati kà ‘Iwe Itan Bibeli’ yin tí mo ra lọwọ́ ọ̀kan ninu awọn Ẹlẹrii tí ó ṣe ibẹwo. Awọn ọmọde naa nífẹ̀ẹ́ ìwé naa, awọn ìtàn rẹ̀, tí wọn sì ńbẹ̀ mi fun pupọ sii nigba ti mo bá fi ìwé naa silẹ.”
Awọn ọmọde kan ha wà tí iwọ mọ̀ tí wọn yoo tún gbadun Iwe Itan Bibeli Mi bí? Bi iwọ ba nifẹẹ lati gbà ẹ̀dà kan iwe yii wulẹ kọ ọ̀rọ̀ kún àlàfo isalẹ yii kí o sì gé e ranṣẹ fun isọfunni. Ìwé naa ní ojú-ìwé 256, ìtóbi ojú-ìwé kan naa pẹlu ìwé-ìròhìn yii, ó sì kún fun ohun tí ó ju 125 awọn àwòrán àpèjúwe títóbi, tí pupọ julọ wọn jẹ́ aláwọ̀ meremere.
Emi yoo fẹ́ lati gba isọfunni nipa bi mo ṣe le gba iwe ẹlẹhin-lile naa Iwe Itan Bibeli Mi.