“Ohùn-orin Tí Ńmúniláradá”
Obinrin kan lati Spain kọ̀wé sí ẹ̀ka Watch Tower ti Germany pe: “Mó kún fun ìmoore gan-an tí ó fi jẹ́ pe mo nilati kọ̀wé lati sọ fun yin nipa rẹ̀.” Eeṣe ti oun fi kún fun ìmoore tobẹẹ?
“Mo ti gbé ní Spain fun nǹkan bii ọdun mẹsan-an,” ni oun ṣalaye, “ọdun kan ati ààbọ̀ sẹhin, meji lára awọn ọ̀dọ́ yin bẹ̀rẹ̀ síi kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu mi. Bí mo ti kà ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan ninu Ilé-ìṣọ́nà nipa ohùn-orin tí ńmúniláradá, mo sọ fun wọn lati gbà awọn kasẹẹti naa fun mi.
“Ní àkókò kan lẹhin igba naa, bí mo ti ńnímọ̀lára ìsoríkọ́ ti mo sì wà ninu ìrora, mo gbé ohùn-orin naa sí i. Ẹ wo ìyàtọ̀ tí ó mú wá! Laaarin àkókò kúkúrú, ìrora ọkàn naa ti lọ, ipò ọkàn mi sì ti sunwọn sii jọjọ. Bawo ni inu mi ti dùn tó lati ní awọn kasẹẹti ohùn-orin wọnyẹn. Lati ìgbà naa wá, nigbagbogbo ni mo maa nfetisilẹ sí wọn ni awọn alẹ́ ti nko ba ri oorun sùn. Ó jẹ́ ohùn-orin tí ńmúniláradá nitootọ.”
Ọpọ eniyan ti wá mọriri alubọọmu naa Sing Praises to Jehovah, tí ó ní kasẹẹti mẹjọ nínú. Bí iwọ bá nifẹẹ sí gbígbà alubọọmu yii kọ ọ̀rọ̀ kún àlàfo tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yii kí ó sì fi ranṣẹ.
Emi yoo fẹ́ lati gba alubọọmu naa Sing Praises to Jehovah tí ó ní kasẹẹti mẹjọ ti teepu olóhùn-orin ninu. (Kọwe si adirẹsi tí ńbẹ nisalẹ fun isọfunni.)