“Eyi ni Ara Mi”
“Ẹ GBÀ Á ki ẹ si jẹ; . . . eyi ni ara mi.” (Matiu 26:26, The New Jerusalem Bible)
Pẹlu awọn ọrọ wọnyi, Jesu Kristi gbe akara alaiwu fun awọn aposteli rẹ̀ nigba ti o pilẹ gbe Ounjẹ Alẹ Oluwa kalẹ̀. Ṣugbọn kinni oun nilọkan nipa awọn ọrọ naa, “Eyi ni ara mi”?
IDAHUN si ibeere yii ṣepataki fun awọn Roman Katolik, niwọnbi awọn ọrọ Jesu ti da idi ipilẹ ẹkọ igbagbọ ìyídà ajara ati waini si ẹran òun ẹjẹ Jesu nibi Mass. Ni ibamu pẹlu igbagbọ yii, nigba ti awọn Katolik bá ṣayẹyẹ Mass ti wọn sì gbé àkàrà pẹlẹbẹ naa mì, o yipada di ara tabi ẹran-ara Kristi gidi. Nitori naa, wọn yoo ṣaifohunṣọkan lọna lilekoko pẹlu New World Translation of the Holy Scriptures, tí ó ṣetumọ awọn ọ̀rọ̀ Jesu pe: “Gbà, jẹ. Eyi tumọsi ara mi.” Itumọ yii mu un wa sọkan pe akara naa jẹ ami iṣapẹẹrẹ ẹran-ara Jesu, kii ṣe ẹran-ara naa funraarẹ. Itumọ wo ni o gbe ironu titọna yọ?
Ọ̀rọ̀ Giriiki naa ti a tumọ sí “ni” tabi “tumọsi” ni e·stinʹ. Ni pataki o tumọsi “ni,” ṣugbọn o tun le tumọsi “lati tọkasi, tumọsi.” Itumọ wo ni o dara ju ninu ayika-ọrọ yii?
Akiyesi ẹsẹ iwe ni Matiu 26:26 ninu èdè Spanish La Sagrada Escritura, Texto y comentario por Profesores de la Compañía de Jesús, Nuevo Testamento I (Iwe Mimọ, Ọrọ ẹsẹ iwe ati Alaye lati ọwọ awọn Ọjọgbọn ẹgbẹ Jesu, Majẹmu Titun) yẹ fun afiyesi. O wipe: ‘Itumọ naa, lati inu oju-iwoye ti gírámà, ni a le tumọ gan an bakannaa si tumọsi tabi ṣapẹẹrẹ gẹgẹbi ni—ti tumọsi ijọra bakannaa ni bi o ṣe ri gan an. Gẹgẹbi awọn apẹẹrẹ ti itumọ naa ti o jẹ ṣapẹẹrẹ, Jẹnẹsisi 41:26; Esekiẹli 5:5; Daniẹli 7:17; Luku 8:11; Matiu 13:38; 16:18; Galatia 4:24; Iṣipaya 1:20 ni a lè tọkasi. Itumọ ni ([ni ero itumọ ti] jọra bakan naa pẹlu) ni a dámọ̀ràn, gẹgẹ bi a ṣe le rii ninu awọn iwe ero igbagbọ ṣọọṣi, yatọsi ṣiṣeeṣe ti afiwe ẹlẹ́lọ̀ọ́, tabi iṣapẹẹrẹ, ati ni ọna ti Ṣọọṣi Ijimiji gba loye àpólà-ọ̀rọ̀ naa pẹlu.’
Gẹgẹbi ẹda itumọ Roman Katolik yii ti fihan laifotitọ pamọ, lọna ti gírámà awọn ọ̀rọ̀ Jesu ni a lè loye ni ọna mejeeji. Niti tootọ, ọ̀rọ̀ Giriiki naa e·stinʹ ni a tumọsi “itumọ ti” nibomiran ninu New Jerusalem Bible ti Katolik. (Matiu 12:7) Ọ̀rọ̀ wo ni olutumọ kan nilati yàn ni Matiu 26:26? Niwọnbi Jesu ṣi ti walaaye ninu ara pipe kan nigba ti oun sọ awọn ọrọ ẹsẹ iwe yẹn, akara naa ti oun pese fun awọn ọmọlẹhin rẹ ko lè jẹ ẹran-ara rẹ gidi. Ju bẹẹ lọ, gbogbo ara ẹda eniyan pipe rẹ lodidi ni a pèsè gẹgẹbi ẹbọ irapada kan. (Kolose 1:21-23) Fun idi yii, itumọ ẹsẹ iwe yii didara julọ ni: “Eyi tumọsi ara mi.” Akara aláìwú naa fami ṣapẹẹrẹ ara Jesu, eyi ti o fẹrẹẹ to fi ṣèrúbọ nitori araye.
Ani bi Bibeli tìrẹ fúnraàrẹ ba ni ọrọ naa “Eyi ni ara mi,” iwọ ko nilati daamu. Jesu lo èdè ti o farajọra niye igba. Nigba ti oun wipe, “Emi ni ilẹkun” ati, “Emi ni àjàrà tootọ,” ko si ẹni ti o loye rẹ pe oun jẹ ilẹkun gidi tabi àjàrà gidi kan. (Johanu 10:7; 15:1) Ati nigba ti, ni ibamu pẹlu The New Jerusalem Bible, oun gbe ife waini fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ ti o si wi pe: “Ife yii ni majẹmu titun naa,” ko si ẹni ti o ronu pe ife naa jẹ majẹmu titun niti gidi. (Luku 22:20) Bakan naa bẹẹ gẹgẹ, nigba ti oun wipe akara naa ‘ni’ ara oun, awa nilati loye rẹ̀ pe akara naa ‘tumọsi,’ tabi ṣapẹẹrẹ, ara rẹ̀.