Iwọ Yoo Ha Gba Ibẹwo Bi?
Ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa yoo fẹ́ lati bẹ̀ ọ́ wò ki o sì ran ọ lọwọ lati mu ìmọ̀ rẹ nipa Ọlọrun, Ijọba rẹ̀, ati awọn ète rẹ̀, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli pọ̀ sii. A ni igbọkanle pe isọfunni yii yoo ran ọ lọwọ, nitori yoo pese awọn idahun ti wọn ṣee gbarale si awọn iṣoro ti gbogbo wa dojukọ lonii Awọn Ẹlẹrii Jehofa
pese itọni ti ara ẹni ati ti awujọ ninu Bibeli laisi idiyele kankan.
Nitori naa bi iwọ yoo ba fẹ́ ki ẹni kan ti o tootun bẹ̀ ọ́ wò ninu ile rẹ, tabi ni ibomiran ti o ba rọgbọ, awa yoo fi pẹlu ayọ̀ ṣeto fun un. A o ran ọ lọwọ lati ri kii ṣe kiki idahun si awọn ibeere Bibeli ṣugbọn idahun si awọn iṣoro ode oni ti a lè yanju nipa fifi awọn ilana Bibeli silo pẹlu. Lati mu araàrẹ wa larọọwọto fun iṣẹ-isin yii, wulẹ kọ ọ̀rọ̀ kún isọfunni ti a beere fun ni isalẹ ki o sì fi ranṣẹ si adirẹsi ti o wà nibi alafo naa.
Emi yoo fẹ́ lati mọ̀ sii nipa Bibeli. Ẹ jọwọ ẹ ṣeto fun ẹni kan lati wa si ọ̀dọ̀ mi.