Iwọ Yoo Ha Gba Ikesini Bi?
Ni ọdun ti o kọja, obinrin kan lati Corpus Christi, Texas, U.S.A., kọwe si Watchtower Society ni Brooklyn, New York, ni wiwi pe: “Orukọ mi ni Emily, mo si ti nkẹkọọ iwe ikẹkọọ tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan fifun mi ni ọsẹ diẹ sẹhin. Lẹhin kika awọn iwe irohin naa ati fifi i wera pẹlu Bibeli idile mi, mo rii pe ko dabi ẹni pe ṣọọṣi Roman Katoliki nkọni ni ohun ti o wa ninu Bibeli Mimọ. Wọn ko sọrọ nipa orukọ Ọlọrun tabi Ijọba Ọlọrun ti nbọ rí, eyi ti mo ri gẹgẹ bi koko ẹkọ pataki ninu Bibeli mi. Mo ti dawọ lilọ si ṣọọṣi idile mi duro mo si ti bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli, ọpẹlọpẹ iwe ikẹkọọ yin ti kii ṣeke.
“Emi yoo bẹrẹ ibakẹgbẹ pẹlu ijọ agbegbe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ẹ jọwọ ẹ ranṣẹ si wọn lati wa si ile mi ki a ba le sọrọ.”
Ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo nitẹẹlọrun lati bẹ ọ wo lati mu imọ rẹ nipa Ọlọrun, Ijọba rẹ̀, ati awọn ete rẹ̀ pọ sii, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli. Lati mu araarẹ wa larọọwọto fun iṣẹ-isin yii, wulẹ kọ ọrọ kun isọfunni ti a beere ni isalẹ yii ki o si fi ranṣẹ si adirẹsi ti o wa ni ibi alafo naa.
Emi yoo fẹ lati mọ sii nipa Bibeli. Ẹ jọwọ ẹ ṣeto fun ẹnikan lati wa bẹ̀ mí wò.