ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/15 ojú ìwé 32
  • Ji! Ṣeranwọ Lati Gbẹbun Eré Ije ni Italy

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ji! Ṣeranwọ Lati Gbẹbun Eré Ije ni Italy
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/15 ojú ìwé 32

Ji! Ṣeranwọ Lati Gbẹbun Eré Ije ni Italy

Ni ọdun ti o kọja ọmọdebinrin ọlọdun mẹwaa kan tí ó jẹ́ ọmọ ile-ẹkọ ni italy kọ arokọ kan ti o ni ẹṣin ọrọ naa “Bi Ilẹ-aye Bá Lè Sọrọ Ni.” Ẹṣin ọrọ naa ni a ṣalaye ni kikun gẹgẹ bi ijumọsọrọpọ laaarin ilẹ-aye ati ọmọ-ọwọ kan ti o beere lọwọ ilẹ-aye idi ti o fi nsunkun. Ọmọbinrin ile-ẹkọ naa ṣalaye pe:

“Ilẹ-aye dahun pe oun ni a ti sọ di eleeri nipa kùrukùru ti o mu iyọrisi ile eweko kan jade. Ilẹ-aye nbaa lọ ni sisọrọ si ọmọ-ọwọ naa o si wi pe laipẹ awọn nǹkan yoo yipada ọjọ ọla rẹ yoo si dara, laifi ti eniyan pè. Ireti ilẹ-aye wa ninu Ọlọrun Olodumare, Ẹlẹdaa rẹ̀, ti ko dá ilẹ-aye lasan ṣugbọn fun un lati di eyi ti a gbe inu rẹ̀.—Aisaya 45:18.”

Ọmọdebinrin ile-ẹkọ naa ṣalaye pe: “Mo mu isọfunni naa lati inu awọn iwe irohin Ji! ti January 22, 1990; March 8, 1990; ati March 22, 1990. Ọpẹlọpẹ awọn iwe irohin wọnyi, ẹṣin ọrọ mi ni o gba ẹbun akọkọ. Ẹbun keji ni ọmọ kilaasi ẹlẹgbẹ mi kan ti iya rẹ jẹ ipa ọna iwe irohin iya mi gba. Oun pẹlu mu isọfunni lati inu iwe irohin Ji! kan naa.

“Mo dupẹ lọwọ yin fun isọfunni didara ti o si peye ti o si tun rọrun ti o mu wa jẹ ọlọgbọn yii. Ẹbun ti mo gba jẹ iye owo 100,000 lire [nǹkan bii $100, U.S.], mo si fi owo yii ranṣẹ lati lo o lati fi tẹ iwe irohin pupọ sii.”

A nimọlara pe laika isin ti o ndarapọ mọ sí, iwọ pẹlu yoo janfaani lati inu awọn ọrọ-ẹkọ fifanimọra ninu Ji!

Emi yoo fẹ ki ẹ fi isọfunni ranṣẹ si mi nipa bi mo ṣe le maa gba iwe irohin Ji! ninu ile mi.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́