Ki Ni Yoo Ṣẹlẹ Si Awọn Ibi Mímọ́ Kristẹndọmu?
AWỌN ti o tẹ̀ iwe naa Holy Places of Christendom, lati ọwọ awalẹ̀pìtàn Stewart Perowne jade beere pe: “Ta ni, laika inu igbagbọ Kristẹni yoowu ti o ti wa si, ni ó lè duro lori oke Kalifari ninu Ṣọọṣi Ajinde [tabi, Ṣọọṣi Iboji Mímọ́] ni Jerusalẹmu laini èrò ibẹru ọlọwọ: nitori nihin-in ninu ibikan ti a fọ̀wọ̀ fun ti a tilẹ jà lé lori fun ọpọ ọrundun, ni ikorijọ Kristẹndọmu gan-an.”
Kò si ẹni ti ó tii lè fẹ̀rí han pe ṣọọṣi yii ni a kọ̀ sori oke Kalifari, nibi ti Jesu Kristi ti kú. Nitootọ, ṣaaju ki Constantine olu-ọba Roomu to pinnu lati kọ́ ṣọọṣi kan sibẹ, ni tẹmpili abọriṣa kan ti gbààyè ibẹ̀. Ju bẹẹ lọ, Jesu wi pe: “Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti ń sin in ko lè ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:24) Iru awọn olujọsin bẹẹ kìí bọwọ fun awọn ibi “mímọ́” ti ara ti a lè fojuri.
Ni akoko kan, Jerusalẹmu ni ọgangan tẹmpili Ọlọrun ó sì tipa bayii jẹ́ ọgangan idari ijọsin mimọgaara. Bi o ti wu ki o ri, nitori aiṣotitọ awọn olugbe ilu naa, Jehofa Ọlọrun pa á tì, gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ. (Matiu 23:37, 38) Jesu tun sọ asọtẹlẹ isọdahoro ọgangan idari isin yẹn, ti ọpọlọpọ ń baa lọ lati kà sí ibi mímọ́. Awọn ọrọ rẹ̀ ni a muṣẹ nigba ti awọn ara Roomu pa Jerusalẹmu ati tẹmpili rẹ̀ run ni 70 C.E.—Matiu 24:15, 21.
Asọtẹlẹ Jesu maa tó ni imuṣẹ giga sii lori gbogbo ilẹ ọba onisin ti Kristẹndọmu laipẹ, eyi ti ó jẹwọ pe ó jẹ́ ibi mímọ́ kan. Kristẹndọmu ati awọn ibi àyè mímọ́ rẹ̀ nisinsinyi dojukọ iparun nipasẹ ipa aṣodisi isin kan ti a ń pe ni “ìríra isọdahoro.” (Daniẹli 11:31) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo fi tayọtayọ pese isọfunni nipa bi iṣẹlẹ adáyàfoni yii yoo ṣe ṣẹlẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ile-ijọsin kekere kan ninu Ṣọọṣi Iboji Mímọ́ naa
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.