Ó Ju Awọn Ọwọ̀n Fifanimọra Lọ
Awọn oluṣebẹwo ni a famọra nipasẹ awọn ọwọ̀n ninu Okun Mediterranean ni Caesarea, ebute-ọkọ igbaani kan lẹbaa etikun Isirẹli. Hẹrọdu Ńlá kọ́ ebute yii ti o sì sọ ilu naa ní orukọ ní ìbọlá fun Kesari Ọgọsitọsi.
Awọn awalẹ̀pìtàn ti hú ọpọjulọ ninu ilu yii jade, papọ pẹlu gbọngan iṣire ńlá rẹ̀. Wọn tun ti lọ si isalẹ omi lati jere ijinlẹ oye nipa bi a ṣe kọ́ apapọ igbekalẹ naa lẹbaa etikun oniyanrin.
Iwe irohin The New York Times (January 8, 1991) rohin ìṣàwárí awọn ọwọ̀n ninu awọn ahoro ààfin kan ti o nà jade sinu okun tẹlẹri. Iwọnyi jẹ́ akanṣe niti pe awọn ikọwe ti ó wà lara wọn darukọ awọn gomina Roomu diẹ ti a kò mọ tẹlẹri. “Oluṣabojuto” awọn ọkọ-okun naa ni a tun mẹnukan, eyi ti ó “jẹ ikọwe akọkọ ti a tii ri rí ti ó tanmọ ebute naa.”
Awọn akẹkọọ Bibeli mọ pe apọsiteli Pọọlu tukọ wọnu etikun yii ni igba ipari irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun meji. Nihin-in ni o gbé pẹlu Filipi ajihinrere, awọn iriri rẹ̀ sì gbọdọ ti fun awọn ọmọ-ẹhin niṣiiri. (Iṣe 18:21, 22; 21:7, 8, 16) A lè ka ọpọ ninu awọn iriri arumọlara soke wọnyi ninu iwe Bibeli naa Iṣe Awọn Apọsiteli.
Nitori naa awọn ọwọ̀n ẹ̀bá etikun wọnyi kii wulẹ ṣe awọn ohun iranti ìtàn ti kò wulo. Wọn mu awọn arakunrin ijimiji awọn Kristẹni wa sọkan wọn, awọn ti wọn fi itara tan ihinrere kalẹ ni awọn etikun ati jade “lọ si apa ibi jijinna julọ ti ilẹ-aye.”—Iṣe 1:8, NW.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Garo Nalbandian