A Fi Tifẹtifẹ Ké Sí Ọ
Iku ọkunrin naa Jesu Kristi ní ohun ti o ju 1,900 ọdun sẹhin jẹ́ iṣẹlẹ kan ti ó ṣe pataki julọ ninu ìtàn. Ó ṣí ireti naa ti jijere ìyè ainipẹkun ninu ipo Paradise silẹ fun gbogbo wa. Lakooko ayẹyẹ ranpẹ kan, Jesu lo waini ati akara aláìwú gẹgẹ bi iṣapẹẹrẹ irubọ onifẹẹ ti ẹda-eniyan rẹ̀. Lẹhin naa ó sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” (Luuku 22:19) Iwọ yoo ha ranti bi?
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi tọyayatọyaya ké sí ọ lati darapọ mọ wọn ninu ṣe ayẹyẹ ajọdun Iṣe-iranti yii. Yoo jẹ́ lẹhin ti oorun bá wọ̀ ni ọjọ ti o ṣe rẹ́gí pẹlu Nisan 14 lori kalẹnda oṣupa ti Bibeli. Iwọ lè lọ sí Gbọngan Ijọba ti o bá sunmọ ile rẹ̀ julọ. Wadii lọwọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni adugbo rẹ fun akoko ati ọgangan ibi naa pato. Ọjọ ayẹyẹ naa ní 1992 yoo jẹ́ Friday, April 17.