Iná Ru Itolẹsẹẹsẹ Ilé Kíkọ́ Kan Soke
“INÁ! Iná! Gbọngan Apejọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń jóná!” Igbe amunitagiri yẹn dún jade ni ọ̀sán ọjọ Friday kan ni October 1989 ni Heerenveen, ilu kan ni ìhà ariwa ẹkùn Netherlands.
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti lo Gbọngan Apejọ meremere yii fun ọdun 11. Ni ohun ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo ipari ọsẹ, ọgọrọọrun ti pejọ sibẹ fun yala apejọ ayika ọlọjọ meji tabi apejọ akanṣe ọlọjọ kan. O ti jẹ ibi ti o dẹnilọrun fun itọni Bibeli.
Jàm̀bá kan ṣẹlẹ nigba ti iṣẹ ń lọ lọwọ lori orule gbọngan naa. Ni ohun ti o fẹrẹẹ jẹ́ ni iwọnba iṣẹju diẹ, iṣẹlẹ ojiji yii yi gbọngan naa pada si ahoro ti a fi ina jó. Bi o ti wu ki o ri, a kún fun ọpẹ, kò si ẹni ti a palara.
Inu wọn bajẹ nipa ipadanu naa ṣugbọn a kò mú wọn lọkan rẹwẹsi, Awọn Ẹlẹ́rìí ṣe awọn ètò fun gbọngan titun kan ni ibi àyè miiran. Wọn rí ọgangan àyè ti o yẹ ni Swifterbant, ni ẹkùn Flevoland. Eyi jẹ ilẹ salalu kan ti a dari omi kuro lori rẹ̀ ni Zuider Zee ilẹ olókè tẹlẹri, ẹsẹ bàtà 16 si isalẹ ibi ti oju okun ti bá ilẹ dọgba.
Nigba ti o fi maa di January 1991 ìpè ró lati bẹrẹ kíkọ́ Gbọngan Apejọ titun. A o kọ́ ọ laaarin May ati September 1991. Ọgọrọọrun Awọn Ẹlẹ́rìí yọnda lati ṣiṣẹ ni ọgangan àyè ilẹ naa, awọn ọdọkunrin diẹ sì rí iweweedawọle naa gẹgẹ bi okuta àtẹ̀gùn si ṣiṣiṣẹsin Jehofa Ọlọrun ni akoko kikun. Ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ wá lati Belgium ati England.
Ile kan ti a ṣọnà rẹ̀ meremere ni a kọ́. Gbọngan awujọ ati ile ounjẹ rẹ̀ ni a yasọtọ nipasẹ ọdẹdẹ ti a fi gilaasi kan òrùlé rẹ̀. Gbọngan naa gan-an gba 1,008 awọn eniyan, 230 awọn miiran sii sì lè wo itolẹsẹẹsẹ naa lori gọgọwú tẹlifiṣọn ni gbọngan ti ó wà ni ẹgbẹ keji.
Lonii, ẹgbẹẹgbẹrun ń sọ pe: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si ori òkè-ńlá Jehofa, oun yoo sì kọ́ wa nipa awọn ọ̀nà rẹ̀.’ (Aisaya 2:2, 3, NW) Gbọngan Apejọ titun yii wulẹ jẹ́ ọ̀kan lara awọn ibi pupọ ti a ti ń funni ni itọni tẹmi ni. Gbọngan Ijọba Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti adugbo jẹ́ omiran. Nibẹ ni iwọ yoo ti ri ikini kaabọ ọlọyaya.