ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/15 ojú ìwé 30-31
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Mú Ẹ̀gàn Kúrò Lórí Orúkọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/15 ojú ìwé 30-31

Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Oju wo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi wo ríra awọn ẹrù ti a jígbé?

Awọn Kristian yẹra fun mímọ̀ọ́mọ̀ ní ipa eyikeyii ninu ríra ọja tabi awọn aṣọ ti a jígbé.

Dajudaju olè jíjà kò tọna. Ofin Ọlọrun fun Israeli sọ laiṣe tabitabi pe: “Iwọ kò gbọdọ jale.” (Eksodu 20:15; Lefitiku 19:11) Bi a bá mú olè kan, oun nilati ṣe ìsanfidípò oniṣẹẹpo meji, mẹrin, tabi marun-un, ni sisinmi lori awọn ipo ayika.

Lati ìgbà laelae, awọn olè ti maa ń gbiyanju lati ta awọn ọjà ti wọn bá jígbé látaré ki wọn baa lè jèrè kiakia ki a má sì mú wọn pẹlu ẹ̀rí ẹ̀bi àìtọ́ wọn. Fun ète yii wọn sábà maa ń ta awọn ẹrù ti wọn jígbé ni ẹ̀dínwó ti ó ṣoro fun ọpọlọpọ awọn oluraja lati kọ̀. Iru aṣa bẹẹ ni ó ti lè wémọ́ ohun ti a kà ni Eksodu 22:1 pe: “Bi ọkunrin kan bá jí akọmaluu, tabi agutan kan, ti o sì pa á, tabi ti o tà á; yoo san akọmaluu marun-un dipo akọmaluu kan, ati agutan mẹrin dipo agutan kan.”

Ni fifoye mọ ohun ti iru awọn ofin bẹẹ dọgbọn tumọsi, Rabbi Abraham Chill kọwe pe: “A kà á léèwọ̀ lati rà tabi gba ohun-ìní ti a jígbé, ani bi a kò bá mọ pe bẹẹ ni ohun-ìní naa rí. Nitori naa ẹnikan kò gbọdọ ra ewurẹ lọwọ darandaran kan, nitori pe darandaran naa ni ó ṣeeṣe ki o ṣe títà naa laijẹ pe agbanisiṣẹ rẹ̀ mọ̀ ki ó sì petepero lati tọju owó naa.”—The Mitzvot—The Commandments and Their Rationale.

Niti gasikiya, ofin Ọlọrun kò ka ‘ríra ewurẹ lọwọ darandaran kan’ léèwọ̀ kìkì nitori ifura pe ó lè tọju owó agbanisiṣẹ rẹ̀, ki o sì wá tipa bẹẹ ta ewurẹ kan ti ó jígbé. Ṣugbọn ni odikeji ọ̀ràn naa, awọn iranṣẹ Jehofa kò gbọdọ dìídì jẹ́ olùkópa ninu ọjà títa kan (ewurẹ tabi ohun eyikeyii miiran) nigba ti ó bá jọ bi ẹni pe ó ṣe kedere pe kì í ṣe olùtajà naa ni ó ni ín tabi pe a lè jí i gbé. Ofin Ọlọrun fihan pe Oun mọyi ohun-ìní àdáni, ṣugbọn olè kan a maa fi ohun-ìní onínǹkan dù ú. Ẹnikan ti ó ra ohun kan ti a ti mọ bi eyi ti a jígbé lè má fi bẹẹ jẹ́ olè, ṣugbọn rira ti o rà á dín ṣiṣeeṣe naa kù pe ẹni ti ó ni ín yoo rí ohun-ìní rẹ̀ gbà pada lae.—Owe 16:19; fiwe 1 Tessalonika 4:6.

Gbogbo wa mọ̀ pe awọn olùrajà ń wà ọ̀nà lati ra ọjà ni iye-owo ti o kéré julọ. Awọn obinrin kari ayé ń wá ọjà títà ti ó lérè, ń gbiyanju lati fi rírajà falẹ̀ titi di akoko ìgbà ti awọn owó-ọjà bá wálẹ̀, tabi ki wọn rajà ni awọn ọjà tabi ṣọọbu ọlọ́pọ̀ ọja ti kò ni náni lowo pupọ ati nipa bayii ni iye-owo ti ó sàn jù. (Owe 31:14) Sibẹ, iru ọkàn ìfẹ́ bẹẹ ninu rírí ìdúnàá-dúrà gbà gbọdọ ni awọn ààlà ti o ba iwa rere mu. Awọn aduroṣinṣin ni ọjọ Nehemiah kọ̀ lati ra ọjà ni Ọjọ Isinmi, ani bi wọn tilẹ lè rí ìdúnàá-dúrà ti ó dara ni awọn ọjọ wọnni. (Nehemiah 10:31; fiwe Amosi 8:4-6.) Ó rí bakan naa pẹlu awọn Kristian. Kíkọ wọn lati jale ràn wọn lọwọ lati ṣekawọ ìdẹwò eyikeyii lati ra awọn ọjà ti owó wọn wálẹ̀ ti o hàn gbangba pe wọn jígbé ni.

Ó lè jẹ́ ohun ti gbogbo eniyan mọ pe awọn olùtajà kan ń lọwọ ninu awọn ẹrù jìbìtì. Tabi iye-owó kan ti a sọ lọna bòókẹ́lẹ́ lè ṣàrà-ọ̀tọ̀ gan-an debi pe eniyan kan ti ori rẹ̀ pe yoo pari ero si pe ọja títà naa ni o ṣeeṣe ki wọn rí lọna ti kò bá ofin mu. Ani ofin ilẹ naa tilẹ lè jẹwọ aini fun iru ìlọ́gbọ́n-nínú bẹẹ. Idipọ iwe ofin kan sọ pe:

“Mímọ awọn otitọ ṣiṣe kókó nipa aibofinmu ìwà kan ti a pe ni ìwà ọdaran ni kò mú un di dandan pe ki ẹni ti a fisun naa mọ ọ̀dọ̀ ẹni ti tabi ta ni ó jí ohun-ìní naa gbé, tabi nigba wo tabi nibo ni a ti jí i gbé, tabi awọn ipo ayika labẹ eyi ti a ti jí i gbé, ṣugbọn ó ti tó pe ó mọ̀ pe a jí i gbé ni. . . . Awọn ile-ẹjọ diẹ gba oju-iwoye naa pe wiwanibẹ otitọ ṣiṣe kókó nipa aibofinmu iwa kan ni a lè gbekari otitọ naa pe olùjẹ́jọ́ naa gba ohun-ìní naa labẹ awọn ipo ayika iru eyi ti yoo tẹ́ eniyan oloye táṣẹ́rẹ́ ati alaikun fun iṣọra lọrun pe a jí i gbé ni.”

Eyi ṣe afikun idi yiyekooro kan fun Kristian lati yẹra fun ríra awọn ọjà ti a jígbé. Rírà ti ó bá ń ra iru awọn ọjà bẹẹ lè sọ ọ́ di arufin. Niti tootọ, ni awọn orilẹ-ede kan ẹnikan ti ń ra awọn ohun ti a jígbé labẹ ipo eyikeyii ni a o kà si ẹni ti o jẹbi rírú ofin. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn kò ni idalẹbi ọkàn nipa rírú ofin bi wọn bá ronu pe awọn lè mú un jẹ. Iyẹn kì í ṣe otitọ nipa awọn Kristian, awọn ti wọn fẹ́ lati “wà ni itẹriba fun awọn alaṣẹ onipo gigaju.” Jíjẹ́ olùpa ofin mọ́ ń daabobo wọn kuro lọwọ ìbánirojọ́ gẹgẹ bi ọdaran, ó sì dákún níní ẹ̀rí ọkàn rere niwaju Jehofa.—Romu 13:1, 4, 5, NW.

Abrahamu ọ̀rẹ́ Ọlọrun gbé apẹẹrẹ rere kalẹ̀ niti ẹ̀rí ọkàn. Ni awọn ọjọ rẹ̀, awọn oluṣakoso ìhà ila-oorun mẹrin ṣẹ́gun awọn ọba ibi ti Loti gbé, ni kíkó ọpọlọpọ awọn ohun aṣeyebiye lọna iru olè jíjà kan ti o jẹ́ ti ologun. Abrahamu, lépa, ó sì bori awọn ọ̀tá naa, ó sì kó awọn ẹrù ti wọn jígbé naa pada. Ọba Sodomu sọ fun Abrahamu pe: “Mú ẹrù fun araarẹ” gẹgẹ bi èrè. Kaka bẹẹ, Abrahamu kó awọn ẹrù naa lé awọn ti ó fi ẹ̀tọ́ ni ín lọwọ, ni sisọ pe: “Emi ki yoo mú ohun kan ti i ṣe tirẹ, ki iwọ ki o má baa wi pe, mo sọ Abrahamu di ọlọ́rọ̀.”—Genesisi 14:1-24.

Awọn Kristian kò ni ọkàn ìfẹ́ ninu anfaani owó eyikeyii ti ó lè ṣeeṣe nipasẹ awọn ẹrù ti a jígbé. Jeremiah kọwe pe: “Bí àparò ti i sàba lori ẹyin ti kò yín, bẹẹ gẹgẹ ni ẹni ti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì í ṣe ni ododo.” (Jeremiah 17:11) Nitori naa, rekọja fifi ọgbọn han nipa ṣiṣai rú awọn ofin Kesari nipa ohun-ìní ti a jígbé, awọn Kristian fẹ́ lati di idajọ ododo Ọlọrun mú nipa kíkọ̀ lati ni isopọ ni ọ̀nà eyikeyii pẹlu aiṣododo ti olè jíjà. Dafidi kọwe lọna ti o dara pe: “Ohun diẹ tí olododo ní sàn ju ọrọ̀ ọpọ eniyan buburu.”—Orin Dafidi 37:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́