ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/15 ojú ìwé 32
  • Wọn Lè Kẹkọọ Lara Awọn Oyin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọn Lè Kẹkọọ Lara Awọn Oyin
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/15 ojú ìwé 32

Wọn Lè Kẹkọọ Lara Awọn Oyin

“Ni awọn ọdun aipẹ yii, awọn oniṣẹ́-ẹ̀rọ ati awọn oníṣọ̀nà lọna ti ó tubọ ń pọ sii ti mọ ohun kan ti awọn oyin lọna ti o hàn gbangba ti mọ tipẹ: ṣiṣeto ohun eelo bín-ín-tín kan si ọnà afárá-oyin onígun mẹfa mú ki o tubọ lagbara ju bi ìbá ti jẹ́ ni irisi miiran.” —The New York Times, October 6, 1991.

KÒ YANILẸNU pe awọn eniyan lè jere lati inu ikẹkọọ awọn kokoro tiṣọratiṣọra. Ọkunrin igbagbọ igbaani kan, Jobu, sọ lẹẹkan ri pe: “Bi awọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ni ẹ̀kọ́, ati ẹyẹ oju ọrun, wọn o sì sọ fun ọ. . . . Ta ni kò mọ ninu gbogbo wọnyii pe, ọwọ́ Oluwa ni o ṣe nǹkan yii?” (Jobu 12:7-9) Bẹẹni, ọgbọn Ẹlẹdaa naa han gbangba ninu iru awọn ohun ti o wọ́pọ̀ bẹẹ gẹgẹ bi irisi onigun mẹfa ti awọn sẹẹli ti iwọ lè ri ninu afárá-oyin.

Nigba ti awọn ìkélé ìda oyin inu awọn sẹẹli wọnyi wulẹ nípọn tó íǹṣì 1/80, wọn lagbara gan-an ni. Niti tootọ, wọn lè faragba ẹrù ti o wuwo lọna 30 ju ìwọ̀n iwuwo wọn lọ.

Okun yii ni a lè múlò ni awọn ọ̀nà gbigbeṣẹ ti ó ṣee fojuri, iru bii rírọ ohun eelo lẹgbẹẹ nitori ikọlu lilagbara. Ó tilẹ ń daabobo ohun eelo ologun ti a fi ń sọ̀kò sori ilẹ̀-ayé. The New York Times ṣakiyesi nipa eyi pe: “Awọn ohun ti o wúwo tó awọn ọkọ̀ jeep ni a dè mọ́ ori pepele pẹlu awọn àkànpọ̀ afára-oyin labẹ rẹ̀ lati faragba ìmìtìtì ti bíbalẹ̀.”

Awọn ohun ti eniyan ṣe pẹlu iṣẹ ọnà yii ni a mú jade lati inu ọpọlọpọ ohun eelo. Eyi ti o wọ́pọ̀ julọ jọbi pe ó jẹ́ bébà. Bébà ọlọ́ràá ati oje igi ni a ń lo lati ṣe afárá-oyin ti o maa ń lọ sinu ara awọn ọkọ̀ ofuurufu ńlá kan. Okun naa ń wá pẹlu ìwọ̀n iwuwo ti ó kere ní ifiwera. Eeṣe? Ọpọ julọ ninu àlàfo ti o wà ninu irin palaba jẹ́ atẹ́gùn, nitori naa ìwọ̀n iwuwo bín-ín-tín ni ó wà. Atẹ́gùn naa sì ni agbara idina mọ́ ooru ti o dara pẹlu.

Oyin lásán làsàn kò “mọ” gbogbo eyi niti gidi, nitori pe kò gba oyè ninu ìmọ̀-ẹ̀rọ. Sibẹ, lojoojumọ ó ń lọ sẹnu iṣẹ rẹ̀ pẹlu ọgbọ́n àdánidá tí Ẹlẹdaa naa, Jehofa pese.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́