ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/1 ojú ìwé 30
  • Wọn Wá Laika Àìfararọ ati Ewu Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọn Wá Laika Àìfararọ ati Ewu Sí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/1 ojú ìwé 30

Wọn Wá Laika Àìfararọ ati Ewu Sí

DÉÈTÌ ọjọ naa ni January 2, 1992. Ibẹ̀—Maxixe, Ẹkùn ipinlẹ Inhambane. Ìró-igbe àṣálẹ́ Africa ti Mozambique ni a jálù lojiji bí redio kan ti di eyi ti a ṣi silẹ. “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe Apejọpọ ‘Awọn Olùfẹ́ Ominira’ wọn ni ẹkùn ipinlẹ wa,” ni olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́ naa kede. “Ète wọn ni lati fun awọn eniyan ni itọni nipa bi wọn ṣe lè ri ominira tootọ ninu ayé lonii. Gbogbo eniyan ni a pè ki ó wa o.”

Nibẹ ní igun Africa jijinna yẹn, ohun manigbagbe kan ń ṣẹlẹ! Fun ìgbà akọkọ, apejọpọ agbegbe ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ń ṣe, 1,024 awọn eniyan sì wà nibẹ lati gbadun rẹ̀. Ni iwọnba ọdun diẹ sẹhin, iru iṣẹlẹ kan bẹẹ ni kò lè ṣẹlẹ ni gbangba bẹẹ ni Mozambique, niwọn bi iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wà labẹ ifofinde nigba naa. Iwọ yoo ha fẹ́ lati gbọ nipa awọn irubọ onigboya ti a ṣe lati lọ si apejọpọ yii bi?

Ẹkùn ipinlẹ Inhambane, bi ọpọlọpọ apa Africa miiran, ni o lẹ́wà lọna ti o kọyọyọ. Ọkọ̀ apẹja ti o ri bii ọkọ̀ oju-omi ńlá ti a ń pè ni dhow ti o ní ìgbòkun-ọkọ̀ onigun mẹta ń rìn loju òkun jinna si ẹ̀bá etikun rẹ̀. Awọn igi àgbọn pọ̀ yanturu. Ṣugbọn èrò nipa ewu buburu kan yika agbegbe igberiko naa: ogun abẹ́lé!

Fun awọn wọnni ti wọn ń sùn ninu ahéré ti a fi imọ̀ ọpẹ kọ́ ni wakati kutukutu òwúrọ̀, o wọpọ pe ki fínrín-fínnrín ìró gbì-gbì-gbì ohun ìjà ńlá ni awọn abule itosi jínikalẹ̀ niwọn bi ogun inu igbo naa ti ń lọ lọwọ ní gbogbo òru. Bi o ti sábà maa ń jẹ́ nigba gbogbo awọn kòmọwọ́-kòmẹsẹ̀ ara ilu ni wọn maa ń jiya. Nigba miiran, awọn ọmọde ni a ń rí ti wọn ń ṣe láńká-láńká lọ pẹlu ẹsẹ tí kò sí tabi ti a ti gé apakan rẹ̀ jùnù. Ani diẹ lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa paapaa ní àpá ni oju ati ni ara wọn lati inu iwa ìkà tí wọn ti jiya rẹ̀.

Labẹ awọn ipo wọnyi Apejọpọ “Awọn Olùfẹ́ Ominira” ni gbogbo awọn ti wọn lọ sibẹ mọriri lọna jijinlẹ. Laika ṣiṣeeṣe naa pe ki a ba deni loju ọ̀nà apejọpọ si, ọpọlọpọ awujọ idile lati awọn agbegbe eréko ni wọn pinnu lati wá. Dídé ibẹ̀ kò rọrun pẹlu, niwọn bi gbogbo eniyan ti sábà maa ń lọ lati ibikan si omiran ni ẹhin ọkọ̀ akẹ́rù ti kò nílélórí. Nigba miiran iye awọn èrò ti wọn tó 400 ni a ń fún mọ́nú ọkọ̀ kan! Ọpọ awọn ọkọ̀ wọnyi tò sori ìlà lati di agbajọ ọkọ̀ aririn-ajo tí awọn ologun adìhámọ́ra ń tẹle.

Nora ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mẹta, ti ọjọ ori wọn jẹ́ ọdun kan, mẹta, ati mẹfa, jẹ́ idile kan ti wọn fi ẹmi wọn wéwu nipa ririnrin-ajo ni ọ̀nà yii. Ó ti tọju owó pamọ fun ọpọlọpọ oṣu ṣaaju ki o baa lè lọ si irin-ajo naa. Otitọ naa pe kò sí awọn ibugbe ti o fidii mulẹ larọọwọto ní apejọpọ naa kò dí i lọwọ. Papọ pẹlu ọpọlọpọ miiran, Nora ati idile rẹ̀ wulẹ se ounjẹ, wọn jẹun, wọn sì sùn lori ilẹ gbalasa gan-an ni ọgangan ibi apejọ naa.

Ki i tilẹ ṣe ooru mimuna ti ilẹ olooru tí ọ̀wààrà òjò alátẹ́gùn tẹ̀lé ni ó lè pami si idunnu kikọyọyọ ti awọn ará ti wọn ń gbadun àsè tẹmi papọ. Wọn nimọlara pe kò sí ohunkohun ti o ṣe pataki fun wọn ju wíwà ni ibi apejọpọ yẹn lọ. Aropọ eniyan 17 fami ṣapẹẹrẹ iyasimimọ wọn ninu omi lilọwọọwọ ti Agbami-okun India. Bi iribọmi naa ti ń lọ lọwọ, ogidigbo awọn onworan alayọ ni a ru soke lẹẹkan naa lati kọ orin iyin si.

Awujọ awọn olujọsin yii ti ṣawari ohun ti o tumọsi lati di olùfẹ́ ominira ti Ọlọrun nitootọ. Hans, ayanṣaṣoju kan lati olu-ilu, Maputo, ti sọ: “A ṣẹṣẹ rí ibẹrẹ sanmani titun ninu iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni apá Africa yii ni.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́