Bii Awọn Ẹyẹle Tí Ń fo Lọ Si Inu Àgò Wọn
BOYA awọn ẹyẹle wà lara awọn ẹyẹ ti eniyan kọkọ sìn ninu ile. Ni ọpọ ẹgbẹrun ọdun sẹhin, awọn ará Egipti—pẹlu èrò lati ni ipese ounjẹ jalẹ ọdun—kọ́ àgò awọn ẹyẹle sẹbaa ile wọn. Ẹran awọn ẹyẹ naa ni a mọriri gidigidi, ìgbẹ́ wọn ni a sì lò gẹgẹ bi ilẹ̀dú. Ni Sanmani Agbedemeji, àgò awọn ẹyẹle jẹ́ iru awọn ohun ìní ti a fẹ́ bẹẹ debi pe ni awọn orilẹ-ede kan kiki awọn ọ̀tọ̀kùlú tabi eto idasilẹ onisin ni a yọnda fun lati ni wọn.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn adiyẹ ti rọpo awọn àdàbà gẹgẹ bi orisun ẹran lori ọpọ julọ tabili ounjẹ nisinsinyi, awọn àgò ẹyẹle igbaani kan ni a ṣì lè bá pade. Awọn àgò ẹyẹle ti a yà soke yii ni a rí ni Egipti.
Bi wọn ba ń fo pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀ bọ̀ ni aṣalẹ, bi igba ti awọsanma awọn ẹyẹ pupọ jaburata gan-an gúnlẹ̀ sori àgò ẹyẹle naa ni o maa ń ri. Wolii Heberu naa Isaiah tọka si eyi nigba ti o beere pe: “Ta ni wọnyi ti ń fò bi awọsanma, ati bi awọn ẹyẹle si ojule wọn?” Gẹgẹ bi itumọ miiran ti sọ ọ́: “Awọn wo niwọnyi tí ń wọ́ lọ bi awọsanma, ti ń fò bi awọn ẹyẹle sinu àgò wọn?”—Isaiah 60:8; The New English Bible.
Idahun naa ni a rí lonii ninu ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun awọn eniyan olubẹru Ọlọrun ti wọn ń wọ́ wá sinu eto-ajọ Jehofa. Ninu Gbọngan Ijọba Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọn kọ́ lati nireti ninu Ọlọrun. (Isaiah 60:9) Laaarin awọn eniyan Ọlọrun, wọn ṣawari pe awọn iniyelori tẹmi, igbagbọ ti o walaaye, ati ibakẹgbẹ pipeye funni ni imọlara alaafia ati ailewu ti o jọ eyi tí ẹyẹle ń rí ninu àgò rẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.