ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 9/1 ojú ìwé 32
  • Ìkórè ti Ajihinrere Tootọ Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkórè ti Ajihinrere Tootọ Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 9/1 ojú ìwé 32

Ìkórè ti Ajihinrere Tootọ Kan

WILLIAM R. Brown kọkọ lọ si Africa ní 1923. Pẹlu aya ati ọmọ rẹ̀, oun ‘ṣe iṣẹ ajihinrere’ ni Gambia, Ghana, Liberia, Nigeria, ati Sierra Leone. (2 Timoteu 4:5) Eso iṣẹ rẹ̀ jẹ alailẹgbẹ.

Ọmọ ibilẹ West Indies yii kì í ṣe mẹmba ṣọọṣi Kristẹndọm, dajudaju oun kò sì lọwọ ninu oṣelu. Dipo bẹẹ, oun ṣafarawe Jesu ati awọn aposteli nipa kikede orukọ ati ipo ọba-alaṣẹ Jehofa, ni titẹnumọ ijẹpataki ẹbọ irapada naa, ati wiwaasu ihinrere Ijọba naa. (Matteu 9:35; 20:28; Johannu 17:4-6) William R. Brown maa ń figba gbo­gbo lo Bibeli, ni titọka si i gẹgẹ bi ọla-aṣẹ ikẹhin ninu awọn ọran ẹkọ-isin ati igbagbọ. (2 Timoteu 3:16) O tẹramọ lilo o debi pe a wá mọ̀ ọn gẹgẹ bi Bible Brown.

Pẹlu ibukun Jehofa, irugbin ti Bible Brown gbìn hù jade o si dagba. Lonii, ni awọn ilẹ ti oun ti ṣe òléwájú, iye ti o tó 200,000 awọn ara Africa ni wọn ti ya igbesi-aye wọn si mimọ si Ẹlẹ́dàá wọn ti wọn si ń waasu ihinrere Ijọba naa fun awọn ẹlomiran. (Matteu 24:14; 1 Korinti 3:6-9) Awọn Kristian ti wọn jafafa wọnyi ni a mọ jakejado fun ìwà ailabosi ati jíjẹ́ ẹni ti o ṣeegbọnkanle. O jẹ ohun àmúyagàn fun wọn lati jẹ Awọn Ẹlẹ́rìí fun Je­hofa ati ọmọ-abẹ Kristi Ọba naa tí ń jọba.

Iru ìkórè kan bẹẹ jẹ abajade ijihinrere ti Kristian tootọ. Iru ìkórè ti o farajọ ọ ni a ń karugbin rẹ̀ yika ayé ni àgbáálá ilẹ kọọkan ti a ń gbé. Ni iye ti o ju 200 ilẹ, iye ti o ju aadọta ọkẹ mẹrin awọn ọlọkan tutu Iọkunrin ati lobinrin ni a ti “kore” ti wọn si ń ṣatunsọ awọn ọrọ angẹli ajihinrere naa pe: “Ẹ bẹru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun; nitori ti wakati idajọ rẹ̀ de.” (Ìfihàn 14:7) Ni tootọ, ọna kanṣoṣo lati ri ireti ninu sanmani oniwahala wa ni lati yiju si Ọlọrun ki a juwọsilẹ fun iṣakoso Ijọba rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́