ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 9/15 ojú ìwé 32
  • Wọn Mọ Orukọ Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọn Mọ Orukọ Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 9/15 ojú ìwé 32

Wọn Mọ Orukọ Ọlọrun

Ẹ̀DÀ iwe akọkọ ti a mọ ti a tii kọ ri ti a si tẹjade ni awọn ilu àgbókèèrè ṣakoso America ti England ni Bay Psalm Book. Itẹjade rẹ akọkọ ni a tẹ̀ lati ọwọ́ Stephen Daye ni Massachusetts Bay Colony ni ọdun 1640. Itẹjade akọkọbẹrẹ ní awọn iwe Bibeli ti Orin Dafidi ninu, ti a tumọ lati inu ede Heberu si ede Gẹẹsi gẹgẹ bi a ti ń sọ ọ ti a si ń kọ ọ ni akoko yẹn.

Apa gbigbafiyesi kan ti Bay Psalm Book jẹ lilo orukọ atọrunwa naa ninu awọn ẹsẹ-iwe melookan. Nipa bayii, ẹnikẹni ti o ba ti ka itẹjade yẹn nigba naa lọhun-un ni 350 ọdun sẹhin wa ni ipo lati mọ orukọ Ẹlẹ́dàá wa. Ninu itẹjade yẹn, fun apẹẹrẹ, Orin Dafidi 83:17, 18 kà pé: “Je ki wọn di ẹni ti a kó idaamu bá titi ayé, ti a si yọ lẹnu gidigidi: bẹẹni jẹ́ ki oju ki o tì wọn, ki a pa wọn rẹ́. Ki awọn eniyan lè mọ; pe orukọ iwọ ẹni ti ń jẹ IEHOVAH nikanṣoṣo, ni ẹni giga julọ ti ó wà lori gbogbo ayé jakejado lati igba pípẹ́ wá.”

Niti tootọ, Ọlọrun ọga-ogo beere ju mímọ̀ ti a mọ̀ pe orukọ rẹ̀ ni Jehofa (Iehovah) lọ. Ninu iwe Bay Psalm Book, Psalm 1:1, 2 sọ pe “ọkunrin alabukun fun” kì í rìn nipa imọran awọn ẹni buburu, “ṣugbọn ninu ofin Iehovah, ni idahun rẹ̀ fun ìyánhànhàn wà.” Ẹ̀dà New England Psalms ti a túntẹ̀ ni 1648 sọ pe: “Ṣugbọn oun lori ofin Jehofa ni o gbé gbogbo inu didun rẹ̀ kà.”

Nihin-in New World Translation of the Holy Scriptures ti ọrundun 20 yii kà pe: “Alayọ ni ọkunrin naa ti kò rìn ni igbimọ awọn ẹni ibi, ti ko si jokoo ni ọ̀nà awọn ẹlẹṣẹ, ni ijokoo awọn ẹlẹya ni oun ko jokoo. Ṣugbọn didun inu rẹ̀ wa ninu ofin Jehofa, ninu ofin rẹ̀ ni oun ti ń ka pẹlu ohùn jẹjẹ lọsan ati loru.”

Lati jẹ alayọ nitootọ, ẹnikan gbọdọ kọ imọran awọn ẹni ibi. Oun ko nilati tẹ̀lé apẹẹrẹ awọn ẹlẹṣẹ kò sì ni darapọ mọ ajọ ẹgbẹ awọn ẹni ẹlẹya alaiwa-bi-Ọlọrun. Laaarin awọn nǹkan miiran, oun nilati yẹra fun ibakẹgbẹpọ awọn ẹni ti imọran ati iwa wọn lè sun un sinu iwa aimọ takọtabo, aṣilo oogun, ati awọn igbokegbodo miiran ti o lodisi ofin Ọlọrun. Bẹẹni, ojulowo ayọ̀ sinmi lori kikẹkọọ nipa Ọlọrun otitọ naa, ẹni ti orukọ rẹ̀ ń jẹ Jehofa, ati ṣiṣe ifisilo ofin rẹ̀ gẹgẹ bi a ti ṣi i paya ninu Bibeli.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́