“Awọn Ọrun Ń Sọrọ . . .”
Ni nǹkan ti o tó 150 million kilomita lati ibi ti o wà nisinsinyi, ni òòrùn ti ń ràn pẹlu itanṣan bí iná ni oju ọrun. Bi a tilẹ ti ń jọsin rẹ̀ gẹgẹ bi ọlọrun fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, ni odikeji, alámùúlégbè wa ologo ti oju ọrun yii jẹ́, ẹ̀rí si agbara Ẹlẹdaa rẹ̀, “ti o dá ọrun oun ayé.” (Orin Dafidi 115:15) Imọlẹ ati imooru rẹ̀ ṣe pataki fun iwalaaye lori ilẹ̀-ayé. Otitọ ti awọn onimọ-ijinlẹ sì ti kẹkọọ nipa rẹ̀ fi iyanu kun ọkàn wa.
A sọ fun wa pe òòrùn ń pese ọpọlọpọ iye okun-inu. Iwọ ha mọ̀ pe kìkì eyi ti o dínkù si ìdajì ninu ìwọ̀n ọ̀nà billion awọn ooru ati imọlẹ ti ó ń mujade ni ayé ń faragba bi? Sibẹ, ìpín yẹn papọ jẹ́ àrágbabú 240,000,000,000,000 ìwọ̀n ipá agbara ẹrọ!
Bawo ni òòrùn ṣe ń mú gbogbo agbara yẹn jade? Nipasẹ ìṣùpọ̀ ìléeru atọmiki ńlá kan laaarin rẹ̀ ti o ń mú agbara jade nipa jíjó nǹkan bii million mẹrin tọọnu awọn hydrogen ni iṣẹju àáyá kọọkan. Lọna ti o dunmọ aráyé ninu, ohun ipese agbara ti o pọ̀ tó wà ninu òòrùn lati mú ki iṣisẹ yii maa baa lọ fun ọpọ billion ọdun.
Awọn ohun kan ti awọn onimọ-ijinlẹ ti ṣawari gbé awọn ibeere dide siwaju sii. Fun apẹẹrẹ, òòrùn ń gbọ̀nrìrì laiduro, bii irin pẹlẹbẹ kan ti a fi òòlù-onirin lù. Eeṣe? Tun gbe eyi yẹwo: Aarin òòrùn ti ń jó fòfò naa ni apa ti o gbona julọ lara rẹ̀ ati pe bi ipele kan ba ṣe jìnnà si aarin rẹ̀ tó, bẹẹ ni yoo ti tutù tó. Ṣugbọn nigba ti a bá wa si ipele ti ó wà nita afẹfẹ ayika òòrùn, corona, iyẹn yipada. Corona naa gbona ju awọn ipele ti o sunmọ aarin ti ń jó fòfò naa. Eeṣe?
Siwaju sii, bi oorun ti ń yipo—bi ayé—awọn apá ọtọọtọ ń yipo ni ìsáré ọtọọtọ. Fun apẹẹrẹ, apa ìta ń yára yipo ju awọn ipele ti o wà ninu. Eeṣe? Bawo si ni iyẹn ṣe ṣeeṣe? Lẹhin naa awọn àbàwọ́n ninu òòrùn tun wà. Awọn àbàwọ́n wọnyi ninu oorun maa ń wá ó sì maa ń lọ ni iyipoyipo ti o wà deedee la saa ọdun 11 já. Eeṣe ti wọn fi ń yipada ni iru ọ̀nà kan ti o wà deedee bẹẹ?
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ṣì wà lati mọ nipa òòrùn, ohun ti a ti mọ̀ ná mú wa wo Ẹlẹdaa rẹ̀, Jehofa, pẹlu ibẹru ọlọ́wọ̀. Gbogbo ìgbà ti a ba rí òòrùn, a rán wa leti pe “awọn ọrun ń sọrọ ogo Ọlọrun; ati ofuruufu ń fi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ han.”—Orin Dafidi 19:1.