Sisọ Asọtẹlẹ Ọjọ-ọla Eto Ọrọ̀-ajé Àgbáyé
AIDURO deedee ọjà eto ọrọ̀-ajé ati ainigbọkanle ninu awọn oluṣayẹwo kulẹkulẹ ti wọn kuna lati sọ asọtẹlẹ iwolulẹ ọjà eto ìdókòwò ní 1987 ti mu ki awọn oniṣowo melookan yiju si iworawọ-sọtẹlẹ lati sọ asọtẹlẹ ọjọ-ọla eto owó wọn, ni iwe-irohin London naa Accountancy Age sọ. Iwe-irohin naa sọ pe “awọn aworawọ-sọtẹlẹ eto owó ti ń jere akọsilẹ ẹgbẹ́ awọn oníbàárà onípò-iyì pupọ gan-an fun asọtẹlẹ wọn lori kulẹkulẹ ipa-ọna igbokegbodo òwò.”
Ẹnikan ti a kàn sí fi awọn iyipo ti oun ti ri ni 30 ọdun akọsilẹ eto owó ojoojumọ wéra pẹlu iṣipopada awọn planeti. Lori ipilẹ yii o funni ní asọtẹlẹ rẹ̀. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oníbàárà ń lọ́tìkọ̀ lati kọbiara si amọran rẹ̀ ṣaaju 1987, nisinsinyi oun ri koda awọn olorikunkun eleto owó ti wọn muratan lati fetisilẹ.
Aworawo-sọtẹlẹ eto owó miiran ya aworan ti a gbekari awọn ọjọ ìbí lati díwọ̀n animọ ẹnikan ati lati ṣawari “ọ̀nà ojútùú si akoko ti idagbasoke iṣowo yoo ṣeeṣe” pẹlu. Sibẹ òmíràn gbagbọ pe iyipada leralera ọjà fàdákà ń tẹ̀lé iyipo oṣupa. Ṣugbọn nigba ti a bá fiwera pẹlu awọn oluṣayẹwo kulẹkulẹ eto owó ti o wọpọ, aworawọ-sọtẹlẹ yii rii pe awọn oníbàárà rẹ̀ fun un “ní ààyè ti o kere gidigidi fun ṣíṣìnà.”
Bi o ti wu ki o ri, asọtẹlẹ kan wà lori eto owó ti o daju pe yoo jẹ́ otitọ, kò si ní ohunkohun ṣe pẹlu iworawọsọtẹlẹ. Asọtẹlẹ yii ni a kọsilẹ ninu Bibeli ti Jehofa sì mísí, Ọlọrun naa ti kò fun araarẹ̀ ní “ààyè fun ṣíṣìnà” rara. O jẹ Ọlọrun ti “kò lè ṣeke.” (Titu 1:2) O mu ki wolii rẹ̀ Esekieli polongo pe: “Wọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn ni a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yoo si lè gbà wọn là ni ọjọ ibinu Oluwa.”—Esekiel 7:19.
Nigba wo ni eyi yoo jẹ́? Nigba “ipọnju nla” ti ń bọ̀ ti Jesu Kristi sọtẹlẹ, eyi ti Esekieli pè ní “ọjọ ibinu Oluwa.” (Matteu 24:21; Esekiel 7:19) Aásìkí eto owó kìí yoo mu lilaaja daju, laika ohun ti awọn aworawọ-sọtẹlẹ lè sọtẹlẹ si. Kiki igbọnkale ninu Jehofa Ọlọrun, Oludande Nla naa, ni o lè mu ailewu daju nigba irugudu yika ayé yii ninu eyi ti a o ti mu gbogbo iwa ibajẹ kuro—ti oṣelu, isin, ati ti iṣowo.—Owe 3:5, 6; Sefaniah 2:3; 2 Peteru 2:9.