ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/1 ojú ìwé 32
  • “Lílì tí Ń bẹ ní Ìgbẹ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Lílì tí Ń bẹ ní Ìgbẹ́”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/1 ojú ìwé 32

“Lílì tí Ń bẹ ní Ìgbẹ́”

AINIṢẸLỌWỌ. Owo ọja ti ń ga sii. Ipo    oṣi. Ikimọlẹ ọrọ̀-ajé. Awọn ọ̀rọ̀    wọnyi ń farahan lọna ti ń ga sii lemọlemọ ninu awọn iwe-irohin. Wọn si fi awọn iṣoro ti araadọta-ọkẹ ń dojukọ hàn bi wọn ṣe ń gbiyanju lati wá jijẹ, aṣọ wíwọ̀, ati ibi ti awọn idile wọn ati ibi ti wọn yoo maa gbé.

Ati onigbagbọ ati alaigbagbọ ni ọ̀rọ̀ naa kàn. Ṣugbọn awọn onigbagbọ ni a kò fi silẹ ni awọn nikan ni kikoju awọn iṣoro wọnyẹn. Jesu, ni sisọrọ fun awọn eniyan onirẹlẹ ti ọgọrun-un ọdun kin-in-ni, sọ wi pe: “Ẹ sá wo ẹyẹ oju ọrun; wọn kìí funrugbin, bẹẹ ni wọn kìí kore, wọn kìí sii kojọ sinu abà, ṣugbọn Baba yin ti ń bẹ ni ọrun ń bọ́ wọn. Ẹyin kò ha sàn ju wọn lọ?”—Matteu 6:26.

Jesu tun sọ pe: “Kiyesi lílì tí ń bẹ ní ìgbẹ́, bi wọn ti ń dagba; wọn kìí ṣiṣẹ, bẹẹ ni wọn kìí ranwu: mo si wi fun yin pe, a kò ṣe Solomoni paapaa ni ọṣọ ninu gbogbo ògo rẹ̀ tó bi ọ̀kan ninu iwọnyi. Ǹjẹ́ bi Ọlọrun bá wọ koriko ìgbẹ́ ni aṣọ bẹẹ, . . . meloomeloo ni kì yoo fi lè wọ yin ni aṣọ?”—Matteu 6:28-30.

Eyi ha tumọsi pe Kristian kan kò nilati ṣiṣẹ fun ounjẹ oojọ bi? Àgbẹdọ̀! Kristian kan ń ṣiṣẹ kárakára bi o bá ti pọndandan tó lati san awọn gbese rẹ̀. Aposteli Paulu sọ pe: “Bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun.” (2 Tessalonika 3:10) Bi o tilẹ ri bẹẹ, Kristian naa ni imoye itọju onifẹẹ Ọlọrun o sì ni igbagbọ pe Baba rẹ̀ ọrun ń ṣọ ọ. Nipa bayii, oun ni a kò ré lẹpa nipa awọn aniyan igbesi-aye. Àní ni awọn akoko ti o lekoko paapaa, o fi awọn ohun tii ṣe akọkọ—awọn ohun ti ẹmi—sipo akọkọ. O gba awọn ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́ pe: “Ṣugbọn ẹ tete maa wa ijọba Ọlọrun naa, ati òdodo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọnyi ni a o sì fikun un fun yin.”—Matteu 6:33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́