ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 3/1 ojú ìwé 30-31
  • Awọn Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Micronesia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Micronesia
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 3/1 ojú ìwé 30-31

Awọn Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Micronesia

BI O TILẸ JẸ PE a yà á sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nipasẹ Òkun Pacific títẹ́rẹrẹ ti o dabi alailopin, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Micronesia ṣì ń dọgbọn lati korajọ lọdọọdun fun “ìtúnmúṣọ̀kan idile.” Nibo sì ni ibi ti awọn ajihinrere ti wọn ń wá lati awọn erekuṣu jíjìnnàréré yii ti ń pade? Lọna ti o ṣe wẹ́kú, ni ibi ti ijọba ibilẹ ti sọ ni Opopona Jehofa ni—adirẹsi ọfiisi ẹ̀ka ti o wà ni Guam labẹ eyi ti wọn ti ń ṣiṣẹsin.

Ni June 1992, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun 56 korijọ si ẹ̀ka naa ki wọn baa lè lọ si Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ̀lẹ́.” Ẹ̀rín kèékèé ati ijumọsọrọpọ alayọ gba afẹfẹ kan bi wọn ti ń sọ awọn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ laelae dọ̀tun ti wọn sì ń dá titun silẹ. Gẹgẹ bi o ti maa ń rí nigba gbogbo, wọn ṣeto araawọn sori àtẹ̀gùn Gbọngan Ijọba naa fun fọto àjọyà ati lẹhin naa wọn jokoo sidii tabili àsè gbọọrọ mẹta lati ṣajọpin ounjẹ ọdọọdun kan fun awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun, eyi ti ibẹwo Albert Schroeder, mẹmba Ẹgbẹ Oluṣakoso, pe afiyesi si lọdun yii.

Fun ọpọ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun, ikorajọpọ ọlọdọọdun yii ni Guam ni anfaani kanṣoṣo ti wọn ní lati fi ile kekere wọn ni ilẹ oloooru silẹ. Iwọnyi sì kéré nitootọ. Erekuṣu Ebeye, ọ̀kan lara awọn Erekuṣu Marshall, ní kìkì hectare 32 ninu. Ile ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Majuro ni awọn ilu Marshall ati ile Kiribati ni awọn Erekuṣu Gilbert wà lori awọn erekuṣu tóóró olomi laaarin, ti ó gùn ti o sì dín si ilaji ibusọ ni fífẹ̀. Nitori naa awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun naa gbadun akoko irin-ajo wọn si Guam lọna ti o dara julọ.

Nigba ti èrò wiwaasu lori erekuṣu àdádó ilẹ-oloooru kan lè dún bi eyi ti o fanimọra julọ, niti tootọ ó jẹ́ ipenija kan ti o jẹ pe awọn diẹ ni wọn gbaradi lati dojukọ ọ. Lọna ti o fanilọkanmọra, kìkì 7 ninu awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun 56 naa ni wọn wá lati Watchtower Bible of Gilead. Ọpọ julọ wá lati Hawaii tabi awọn ilu Philippines nibi ti wọn ti jẹ́ ojiṣẹ aṣaaju-ọna tí igbesi-aye ni awọn ilẹ oloooru ti mọlara, wọn sì lọ taarata lati ilẹ orilẹ-ede wọn si ibi-iṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti a yàn fun wọn.

Nitori pe awọn erekuṣu Micronesia wà sunmọ agbedemeji ilẹ̀-ayé tobẹẹ, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ń fàyà rán ooru ati ọ̀rinrin aséniléèémí lati mú ihinrere naa dé ọ̀dọ̀ awọn eniyan. Ijumọsọrọpọ tun lè jẹ́ ipenija kan ti o tubọ ga paapaa. Erekuṣu kọọkan tabi awujọ erekuṣu ní èdè tirẹ̀—awọn kan kò ṣee mọ̀ a kò kọ wọn silẹ ninu iwe-atumọ èdè paapaa—ó sì lè tó ọpọlọpọ ọdun ki ṣẹ̀ṣẹ̀dé kan tó lè sọ ọ́ daradara. Lati ran awọn eniyan ninu erekuṣu ti ó ni iṣẹdalẹ pupọ wọnyi lọwọ lati loye Bibeli, ẹ̀ka Guam ń tẹ iwe-ikẹkọọ ni èdè 11, ti a ń sọ 9 ninu rẹ̀ ni Micronesia nikan.

Awọn erekuṣu kan wà ni àdádó debi pe a lè dé ibẹ kìkì nipasẹ ọkọ̀ òbèlè. Ile awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun Tol ni Chuuk (Truk) ni ó wà lori iru erekuṣu kan bẹẹ, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun nibẹ sì gbarale ipese iná manamana ti a ń pese nipasẹ agbara-oorun fun kìkì iwọnba wakati diẹ lojoojumọ.

Lapapọ, ile ojihin-iṣẹ-Ọlọrun 14 ni ó wà jakejado Micronesia, eyi ti o ni apapọ ayika ti ó fẹrẹẹ tó gbogbo ààlà-ilẹ̀ erekuṣu keekeeke United States nikan. Ninu iye ti o ju 400,000 awọn eniyan ti wọn ń gbé ni ẹkùn naa, 1,000 ni wọn jẹ́ akede ihinrere, ti a ṣetojọ si 20 ijọ ati awujọ àdádó 3.

Nigba ti awọn eniyan Micronesia jẹ́ ẹni bi ọ̀rẹ́ gan-an ni gbogbogboo, awọn aṣa isin adugbo ati ikimọlẹ idile ń kó irẹwẹsi bá ọpọlọpọ lati maṣe tẹwọgba otitọ ti Ijọba Ọlọrun. Nitori naa bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ iwaasu naa ń gbèrú latokedelẹ (awọn 1,000 akede Ijọba wọnni ń dari 2,000 àlékún iye awọn ikẹkọọ Bibeli), awọn ijọ ati awujọ kan ṣì wà ni kekere sibẹ. Fun apẹẹrẹ, kìkì akede 5 ni ó wà lori erekuṣu Tinian, akede 7 pere lori erekuṣu Nauru, ti ọkọọkan awọn ijọ ni Yap, Kosrae, ati Rota sì ni iye akede ti ó dín si 40. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti wà lẹnu iṣẹ-ayanfunni wọn fun ohun ti o ju 20 ọdun lọ. Lọna ti o yẹ fun afiyesi, gbogbo awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun mẹfẹẹfa ti wọn wà lori erekuṣu Belau ti wà nibẹ fun ọdun 12 ó keretan.

Fun awọn wọnni ti wọn farada a, èrè naa pọ̀. Awọn anfaani ojoojumọ wa lati kọ hà si ẹwà awọn iṣẹda Jehofa. Awọn erekuṣu Micronesia ti ń funni ni itura ńláǹlà wà gátagàta kaakiri bii awọn ohun ọ̀ṣọ́ aláwọ̀ eweko lori ipilẹ aláwọ̀ búlúù ti Pacific. Ọpọ ibusọ awọn etikun ti kò kún fọ́fọ́ ati awọn òkúta iyùn ti ń gbá yìn-ìn fun awọn ẹja aláràbarà fa awọn ti ń wẹ̀ nisalẹ omi pẹlu ohun eelo ti a fi ń mí labẹ omi ati awọn ti wọn ni ìtara ọkàn fun ohun-eelo ti a fi ń luwẹẹ ninu omi mọra lati lọ sibi diẹ lara awọn ọ̀gangan iluwẹẹ ti wọn yànláàyò julọ ni ayé. Ati ni opin ọjọ kọọkan, iran agbanilafiyesi ti wíwọ̀ oorun ń bẹ loju òkun.

Èrè titobi julọ, bi o ti wu ki o ri, ni anfaani ṣiṣiṣẹsin Jehofa nipa sisọ fun awọn ẹlomiran nipa awọn ileri agbayanu rẹ̀ fun ọjọ-ọla. Nitori pe awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Micronesia ń nàgà fun èrè yẹn lemọlemọ, wọn ń mú awọn ọ̀rọ̀ Isaiah 42:12 ṣẹ pe: “Jẹ ki wọn fi ògo fun Oluwa, ki wọn sì wi iyin rẹ̀ ninu erekuṣu.”

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Barrigada, Guam

Santa Rita, Guam

Koror, Belau

Dublon, Chuuk (Truk)

Moen, Chuuk (Truk)

Faro Tol, Chuuk (Truk)

Tarawa, Kiribati

Lelu, Kosrae

Ebeye Awọn Erekuṣu Marshall

Majuro

Kolonia, Pohnpei

Songsong, Rota

Chalan Kanoa, Saipan

Yap

MICRONESIA

MELANESIA

AWỌN EREKUṢU CAROLINE

ÒKUN PACIFIC

PHILIPPINES

NEW GUINEA

ÌLÀ-AGBEDEMÉJÌ-ÌBÚ-AYÉ

[Àwòrán]

Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun pejọ ni Guam, June 1992

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́