Iṣẹlẹ Ti Ó Ṣe Pataki Julọ Ninu Ìtàn
Eeṣe ti o fi jẹ bẹẹ? Iṣẹlẹ naa ni iku Jesu Kristi.
Ó ṣiṣẹ lati dá ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun láre ó sì jẹ́rìí si i pe eniyan lè pa iwatitọ pipe si Ọlọrun mọ́. Ó ṣí ireti gbigba ìyè ainipẹkun ninu awọn ipo paradise silẹ fun araye. Jesu funraarẹ dá iṣe-iranti iku rẹ̀ silẹ ni alẹ́ ti o ṣaaju ikú rẹ̀.
Ó jẹ́ ajọdun rírọrùn kan. Lakooko rẹ̀, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” (Luku 22:19, 20) Iwọ yoo ha ranti bi? Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa késí ọ lati darapọ mọ́ wọn lati pa iṣẹlẹ ti o ṣe pataki julọ ninu ìtàn yii mọ́. Ni ọdun yii ọjọ naa jẹ Tuesday, April 6, lẹhin ti oòrùn bá wọ̀.
Jọwọ wadii wò ni Gbọngan Ijọba ti o bá sunmọ ọ fun akoko ati ibi ti a o ti ṣe e. Kò sí idawo kankan ti a o gbà, awọn alejo ni a sì ké sí lati fetisilẹ si ọrọ-asọye afunninitọọni kan ki wọn sì kiyesi awọn igbesẹ rírọrùn naa.