Ọpa-alade Pomegranate Lati Inu Ilé Jehofa Ni Bi?
AWỌN awalẹ̀pìtàn ni Israeli ti ṣawari ọpọ ọpa-alade, awọn ọpa ti awọn ẹni ti o wà lori aṣẹ ń gbé dani. (Genesisi 49:10; Esteri 8:4; Ezekieli 19:14) Awọn ọpa-alade melookan ti a ri ni Lakiṣi ní ori ti o ni irisi pomegranate. Awọn eniyan Ọlọrun nigba naa lọhun-un mọ èso yii daradara.—Deuteronomi 8:8; Orin Solomoni 4:13.
Ehin erin pomegranate naa ti o wà ní ipele ìrudi, lapa òsì, ni a ṣawari rẹ̀ laipẹ yii. O jẹ́ 43 mìlímítà ni giga, ihò kan ti o wà ni isalẹ rẹ̀ sì dábàá pe o jẹ apakan ọpa-alade kan. Ṣakiyesi awọn lẹ́tà ti a kọ́ ni ọ̀nà igbakọwe ijimiji Heberu ti o pẹ́ tó ọrundun kẹjọ B.C.E.
Apakan ehin erin naa fọ́ danu ni ìgbà laelae, nitori naa awọn lẹ́tà diẹ ti sọnu tabi kiki apakan ni o wà nibẹ. Sibẹ, awọn ògbógi ninu ikọwe igbaani dábàá imupadabọsipo naa ti a yà sisalẹ yii. (Ti a gbekari iwe Biblical Archaeologist) Awọn alafo gátagàta ti o wà laaarin awọn lẹ́tà naa ti ṣamọna si kíkà meji pataki. Ọmọwe ilẹ̀ France naa André Lemaire funni ní kíkà naa “O jẹ ti Tẹm[pili Oluw]a [Yahweh], mímọ́ fun awọn alufaa.” Nahman Avigad dábàá “Ọrẹ mímọ́ ọlọ́wọ̀ fun awọn alufaa (ninu) Ile Yahweh.”
Awọn ati awọn ọmọwe miiran pari-ero si pe ọpa-alade naa ni ipilẹṣẹ ní awọn ọ̀rọ̀ Heberu mẹrin ti orukọ ara-ẹni ti Ọlọrun—Jehofa. Nitori naa o ti nilati mẹnukan “ile OLUWA,” gbolohun ọ̀rọ̀ kan ti o wọpọ ninu Bibeli.—Eksodu 23:19; 1 Ọba 8:10, 11.
Ọpọ ṣì nimọlara pe ori ọpa-alade yii ni o ti lè jẹ́ ti alufaa kan ni tẹmpili naa ti Solomoni kọ́ tabi pe a fi ta tẹmpili naa lọ́rẹ. Lọna ti o runilọkansoke, iṣẹ́-ọnà pomegranate naa ni a sábà maa ń ri ninu tẹmpili Ọlọrun.—Eksodu 28:31-35; 1 Ọba 7:15-20.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Israel Museum, Jerusalem