Eeloo Ni Iwọ Yoo San fun Eyi?
IWỌ ha mọ nipa ohun kan ti o ṣeyebiye tobẹẹ debi pe iwọ yoo fi imuratan fi gbogbo ohun ti o ni rubọ ki o baa lè ní i? Jesu mọ̀ ọ́n, ó sì sọrọ nipa rẹ̀ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀.
Ó sọ pe: “Ijọba ọrun sì dabi ọkunrin oniṣowo kan, ti ń wá perli ti o dara. Nigba ti o rí perli olowo iyebiye kan, o lọ, ó sì ta gbogbo nǹkan ti o ní, ó sì rà á.”—Matteu 13:45, 46.
Oniṣowo yẹn muratan lati yááfì gbogbo nǹkan ki o baa lè ní “perli,” Ijọba Ọlọrun naa. Eeṣe? Nitori pe kò sí ohunkohun ninu ayè yii ti a lè fi wé e. Ijọba Ọlọrun yoo yanju awọn iṣoro ti eniyan kò tíì lè yanju, iru bi ogun, ebi, iwa-ipa, ati itẹniloriba. (Orin Dafidi 72:4-8, 13, 14) Labẹ Ijọba naa, àní ẹṣẹ, aisan, ati iku kò ni sí mọ́. (Ìfihàn 21:4, 5) Abajọ ti adura-ẹbẹ keji ninu Adura Oluwa (adura “Baba Wa Ti Ń Bẹ Ni Ọrun”) fi jẹ́, “Ki ijọba rẹ de”!—Matteu 6:9, 10.
Ki ni iwọ yoo san lati ṣajọpin ninu awọn ibukun Ijọba naa? Niti tootọ, ọ̀fẹ́ ni awọn ibukun naa. Ṣugbọn ki o baa lè gbadun wọn, iwọ nilati mọ ohun ti Ijọba naa jẹ́, gbagbọ pe otitọ gidi ni, ki o sì fi i si ipo akọkọ ninu igbesi-aye rẹ. Iwọ ha lè ṣe iyẹn bi? Isọfunni ti yoo ràn ọ lọwọ wà ninu Bibeli. Eeṣe ti o kò fi faaye gba awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati ṣetilẹhin fun ọ ninu kikẹkọọ nipa Ijọba Ọlọrun ati ninu wiwadii bi ó ti lè ṣanfaani fun ọ àní nisinsinyi paapaa.