ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 5/15 ojú ìwé 30
  • Yẹra fun Ẹmi Ìgbéraga!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yẹra fun Ẹmi Ìgbéraga!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 5/15 ojú ìwé 30

Yẹra fun Ẹmi Ìgbéraga!

Owe ọlọgbọn kan ninu Bibeli sọ pe: “Ẹni ti o kọ́ ẹnu-ọna rẹ̀ ga, ó ń wá iparun.” (Owe 17:19) Ki ni ohun ti o buru ninu ẹnu-ọna giga? Ki si ni kókó pataki inu owe yii?

NI awọn ìgbà laelae awọn ẹnikọọkan ati awọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí ti wọn ń gẹṣin kò ṣaiwọpọ. Awọn ile ti a kò bá daabobo ninu awọn ilu gbayawu ṣí silẹ fun awọn olè. Lati dena jíjí awọn ohun-ìní wọn lọ, awọn onile kan ń kọ́ ogiri ti ó ní akanṣe ẹnu ọ̀nà òde. Ogiri naa ga, ṣugbọn ẹnu ọ̀nà àbájáde kuru. Nitootọ, awọn kan kò ju ẹsẹ bata mẹta lọ ni giga—o ti kere ju fun ẹṣin kan ati ẹni ti ń gùn ún lati gbà ibẹ wọle. Awọn wọnni ti wọn kò jẹ ki ẹnu-ọna ti o wọnu agbala wọn kuru dagbale ewu jijẹ ki awọn agẹṣin ọkunrin wọle ki wọn sì piyẹ́ ẹrù wọn.

Ninu awọn agbala ilu-nla ẹnu-ọna maa ń kuru ni gbogbogboo kìí sìí fanimọra, ni ṣiṣaifi itọka kankan hàn nipa ọrọ̀ ti ó lè wà ninu agbo-ile kan ti a fi gbàgede yika. Bi o ti wu ki o ri, ni Persia ẹnu ọ̀nà àbájáde giga fiofio kan jẹ́ ọ̀kan lara awọn àmì ile-ọba, eyi ti awọn ọmọ-abẹ ijọba kan ń gbiyanju lati ṣafarawe rẹ̀ lọna ti o lewu gidigidi. Ẹnikẹni ti o bá ṣe ẹnu ọ̀nà àbájáde giga fun ile rẹ̀ ń késí awọn adigunjale nitori ìfihàn aasiki rẹ̀.

Owe 17:19 tipa bayii fihàn pe awọn wọnni ti wọn ń jẹ ki ẹnu-ọna wọn ga ń fi ainironu dagbale ewu ìjábá nipa bíbu iye lé araawọn kọja bi wọn ṣe tó niti gidi. Owe yii tun lè dọ́gbọ́n tọkasi ẹnu gẹgẹ bi ẹnu-ọna ti a kọ́ ga nipa awọn ọ̀rọ̀ ìfọ́nnu ati onigbeeraga. Iru awọn ọ̀rọ̀ bẹẹ ń mú rogbodiyan gbèrú ó sì lè ṣamọna onigbeeraga naa sinu ìjábá. Ó ti bá ọgbọ́n mu tó, nigba naa, lati yẹra fun ẹmi igberaga!

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Picturesque Palestine, Sinai and Egypt, Idipọ 1, lati ọwọ́ Colonel Wilson (1881)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́