‘Títọ Èèrùn Lọ’ Ti Jẹ́?
ỌLỌGBỌN Ọba Solomoni ti Israeli igbaani funni ni amọran yii pe: “Tọ èèrùn lọ.” Eeṣe ti oun fi sọ eyi? Ki ni a lè kọ́ lara awọn èèrùn?
Solomoni fikun un pe: “Kiyesi ìṣe [èèrùn] ki iwọ ki o sì gbọ́n. Ti kò ni onidaajọ, alaboojuto, tabi alakooso. Ti ń pese ounjẹ rẹ̀ ni ìgbà ẹ̀rùn, ti o sì ń kó ounjẹ rẹ̀ jọ ni ìgbà ikore.” (Owe 6:6-8) Awọn ọ̀rọ̀ ìgbà laelae wọnyi fi otitọ ti awọn onimọ ijinlẹ nipa awọn ohun alaaye ode-oni ṣawari hàn.
Aguri olówe naa fihàn pe awọn èèrùn “gbọ́n.” (Owe 30:24, 25) Dajudaju, ọgbọ́n wọn kìí ṣe imujade ironu ọlọgbọnloye ṣugbọn o jẹ́ abajade ọgbọ́n àdánidá eyi ti Ẹlẹdaa ti fi jinki wọn. Nitori ọgbọ́n àdánidá, fun apẹẹrẹ, awọn èèrùn ń kó ounjẹ wọn jọ ni akoko ti ó tọna.
Awọn èèrùn wà letoleto lọna agbayanu. Wọn ń fọwọsowọpọ lọna pipẹtẹri wọn sì ń tẹtisilẹ si awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ wọn, wọn ń ṣetilẹhin fun awọn èèrùn ti o farapa tabi ti ó rẹ̀ pada wọnu iho wọn lọ. Wọn ń murasilẹ fun ọjọ-ọla pẹlu ọgbọ́n àdánidá wọn sì ń ṣe gbogbo ohun ti o bá ṣeeṣe lati ṣe aṣepari awọn iṣẹ wọn.
Ipa-ọna àdánidá awọn èèrùn dọgbọn fihàn pe awọn eniyan nilati wewee ṣaaju ki wọn sì jẹ́ oṣiṣẹ kára. Eyi kan awọn igbokegbodo ile-ẹkọ, ibi iṣẹ, ati tẹmi. Bi èèrùn ti ń janfaani lati inu akitiyan rẹ̀, bẹẹ ni Ọlọrun ṣe ń fẹ́ ki awọn eniyan ‘rí rere lati inu gbogbo làálàá wọn.’ (Oniwasu 3:13, 22; 5:18) Bi awọn èèrùn ti ọwọ́ wọn dí, awọn Kristian tootọ ń ṣe iṣẹ ti o tó iṣẹ ni òòjọ́. Wọn ‘ń fi agbara ṣe ohun ti ọwọ́ wọn rí ni ṣiṣe,’ kìí ṣe nitori pe alaboojuto kan ń wò wọn, ṣugbọn lati inu ailabosi ati ìfẹ́-ọkàn lati jẹ́ alakitiyan, oṣiṣẹ ti ń mérè wọle.—Oniwasu 9:10; fiwe Owe 6:9-11; tun wo Titu 2:9, 10.
Awa yoo layọ, nitootọ, bi a ba “tọ èèrùn lọ” ti a sì fi ohun ti a kọ́ lati lọ́dọ̀ rẹ̀ silo. Ayọ titobi julọ yoo sì jẹ́ tiwa bi a bá fi taapọntaapọn ṣe ifẹ-inu Jehofa Ọlọrun, gẹgẹ bi a ṣe fihàn ninu Bibeli.