ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/15 ojú ìwé 31
  • Iwọ Ha Ranti Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwọ Ha Ranti Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Jèhófà Pè É Ní “Ọ̀rẹ́ Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ábúráhámù Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • “Ẹ Fìdí Ọkàn-àyà Yín Múlẹ̀ Gbọn-in”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/15 ojú ìwé 31

Iwọ Ha Ranti Bi?

Iwọ ha ri awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ẹnu aipẹ yii gẹgẹ bi eyi ti o ni iniyelori gbigbeṣẹ fun ọ bi? Nigba naa eeṣe ti o kò dán agbara iranti rẹ wò pẹlu awọn ibeere ti o tẹle e wọnyi:

▫ Bi èrò iwapalapala eyikeyii bá wọnu ọkàn wa lairotẹlẹ, ki ni a gbọdọ ṣe? A gbọdọ yí koko-ọrọ naa pada kuro ninu ọpọlọ, nasẹ̀ lọ, kàwé diẹ, tabi ki a ṣe awọn iṣẹ ilé pẹẹpẹẹpẹ kan. Adura tun jẹ́ iranlọwọ alagbara pataki ninu iru ọ̀ràn bẹẹ. (Orin Dafidi 62:8)—4/15, oju-iwe 17.

▫ Eeṣe ti awọn ọ̀dọ́ fi nilati ṣọra nipa iru awọn orin ti wọn ń tẹ́tí si? Orin ní agbara lati ru imọlara soke, lati wọnilọkan patapata, ati lati nipa léni lori. Niwọn bi o ti jẹ pe ọpọ awọn orin gbigbajumọ ní iye ẹ̀dà-ọ̀rọ̀ idibajẹ ti ibalopọ takọtabo ati idọgbọn tọkasi iwapalapala ninu, o rọrùn lati ri i pe a gbọdọ lo iṣọra gidigidi ní yiyan awọn rẹkọọdu, teepu, ati awọn àwo orin.—4/15, oju-iwe 20 si 21.

▫ Ki ni ọ̀rọ̀ naa “wíwàníhìn-ín Oluwa wa Jesu Kristi” tumọsi? (1 Tessalonika 5:23) Eyi ń tọka si wíwàníhìn-ín alaiṣeefojuri ọlọba ti Oluwa Jesu Kristi gẹgẹ bi Ọba, lati 1914 wá, ati tẹle ìgbégorí ìtẹ́ rẹ̀ ni ọ̀run. (Orin Dafidi 110:1, 2)—5/1, oju-iwe 11.

▫ Ète wo ni fífọ̀ ti Jehofa fọ tẹmpili tẹmi rẹ̀ mọ́ ṣiṣẹ fun? (Malaki 3:1-4) Jehofa fẹ́ ki tẹmpili rẹ̀ wà ni ipo mimọ ki o baa lè jẹ́ pe nigba ti a bá mu iye awọn olujọsin nla ti wọn ni ireti ti ori ilẹ̀-ayé wá si ibẹ, wọn yoo ri ibikan ti a ti ń bọwọ fun ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀, ibikan ti a ti ń ya orukọ atọrunwa rẹ̀ si mimọ, ati ibi ti a ti ń ṣegbọran si awọn ofin òdodo rẹ̀.—5/1, oju-iwe 16.

▫ Ki ni “gbogbo ohun-ìní” ti Kristi Jesu fifun awọn ẹrú rẹ̀ ti ó yàn sipo? (Matteu 24:45-47) “Gbogbo ohun-ìní” wọnyi tọka si gbogbo awọn ọrọ̀-ìní tẹmi lori ilẹ̀-ayé ti wọn ti di ohun-ìní Kristi ni isopọ pẹlu ọla-aṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Ọba ti ọ̀run. Eyi yoo ni ọla-aṣẹ ti sisọ awọn eniyan lati inu awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo di ọmọ-ẹhin Kristi ninu. (Matteu 28:19, 20)—5/1, oju-iwe 17.

▫ Bawo ni awọn Kristian alagba ṣe lè fi ‘imuratan’ hàn ní ṣiṣe oluṣọ-agutan, ni ibamu pẹlu ìrọni Peteru ni 1 Peteru 5:2? Kristian alagba kan ti ń bojuto awọn agutan yoo ṣe iṣẹ oluṣọ-agutan rẹ̀ pẹlu imuratan, lati inu ominira ifẹ-inu tirẹ̀ funraarẹ, labẹ idari Oluṣọ-Agutan Rere naa, Jesu Kristi. Ṣiṣiṣẹsin pẹlu imuratan tun tumọsi pe Kristian oluṣọ-agutan kan ń tẹriba fun àṣẹ Jehofa o sì ń fi ọ̀wọ̀ hàn fun iṣeto iṣakoso Ọlọrun.—5/15, oju-iwe 20.

▫ Ki ni Jesu ni lọkan nigba ti o wi pe ẹnikẹni ti o bá ń tọ oun lẹhin nilati “sẹ́ ara rẹ̀”? (Matteu 16:24) Lati ‘sẹ́ ara rẹ’ tumọsi pe ki o fi ẹtọ níni araarẹ silẹ fun Jehofa. (1 Korinti 6:19, 20) O tumọsi pe ki o walaaye, kìí ṣe lati tẹ́ ara rẹ lọrun, ṣugbọn Ọlọrun. (Romu 14:8)—6/1, oju-iwe 9.

▫ Ki ni ohun ti o lè mu ẹnikan layọ? Gbigbadun ibatan rere pẹlu Jehofa ki o sì maa mu ọwọ́ rẹ dí ninu iṣẹ-isin rẹ̀ ń mu ayọ tootọ wá sinu igbesi-aye ẹnikan.—6/1, oju-iwe 22.

▫ Eeṣe ti Jehofa fi faaye gba Abrahamu lati bá oun sọrọ ni falala bẹẹ nipa ète Rẹ̀ lati pa Sodomu run? (Genesisi 18:22-32) Idi kan ni pe Abrahamu jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọrun. (Jakọbu 2:23) Siwaju sii, Jehofa mọ̀ nipa awọn imọlara idaamu ti Abrahamu ní. Ọlọrun mọ̀ pe ọmọ ẹgbọn Abrahamu, Loti, gbé ní Sodomu ati pe Abrahamu daniyan gan-an nipa aabo Loti. Nitori awọn idi wọnyi, Jehofa ṣetan lati dahun awọn ibeere Abrahamu nipa ète Rẹ̀ lati pa Sodomu run.—6/15, oju-iwe 16.

▫ Ǹjẹ́ Iṣatunṣe Protẹstanti ti ọrundun kẹrindinlogun ha sami si ipada si isin Kristian tootọ bi? Bẹẹkọ, kò ṣe bẹẹ! Dipo ki ó mu ipada si isin Kristian tootọ wá, Iṣatunṣe naa ti ṣàmújáde ọpọlọpọ awọn ṣọọṣi jakejado orilẹ-ede tabi ti ààlà ipinlẹ ti wọn ti wá ojurere lọna ẹ̀tàn pẹlu awọn ijọba orilẹ-ede oṣelu ti wọn sì fi taapọntaapọn kọwọti wọn lẹhin ninu awọn ogun wọn.—7/1, oju-iwe 10 si 11.

▫ Ki ni awọn “iṣura ni ọ̀run” ti Jesu sọrọ nipa rẹ̀ ninu Matteu 6:20? Iwọnyi ni awọn iṣura ti kìí ṣá, ti o ní ninu titikan orukọ rere pẹlu Jehofa ati akọsilẹ iṣẹ-isin Kristian tootọ. Iwọnyi wà lara awọn ohun ti Jehofa kò jẹ́ gbagbe. (Heberu 6:10)—7/1, oju-iwe 32.

▫ Awọn animọ wo ni Peteru mẹnukan gẹgẹ bi apá ṣiṣekoko fun igbagbọ wa? (2 Peteru 1:5-7) Peteru sọ pe iwafunfun, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijaanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ ni a gbọdọ fikun igbagbọ wa.—7/15, oju-iwe 13.

▫ Awọn ikilọ wo fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ni ó wà ninu akọsilẹ ẹ̀ṣẹ̀ Dafidi pẹlu Batṣeba? (2 Samueli 11:2-4) Bi o tilẹ jẹ pe ó lominira lati jẹ igbadun ninu igbeyawo tirẹ̀ funraarẹ, Dafidi jẹ́ ki ifẹ fun ibalopọ takọtabo tí kò bofinmu dagba. Ni kikiyesi bi aya Uriah ti fanimọra tó, o kuna lati kó èrò—ati iṣe—ti wíwá igbadun ti kò bofinmu pẹlu rẹ̀ nijaanu. Ohun kan-naa lè ṣẹlẹ si eyikeyii ninu awọn iranṣẹ Ọlọrun bi oun kò bá sára fun iru oriṣi ìwọra yii. (Jakọbu 1:14, 15)—8/1, oju-iwe 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́