Ìwọ Ha ti Kun Ìgbẹ́ Rí Bí?
DÁJÚDÁJÚ BẸ́Ẹ̀KỌ́, ni ìwọ wí. Ṣùgbọ́n dúró ná! Bóyá ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀. Fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ Jakọbu ọmọ-ẹ̀yìn pé: “Ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọ́nnu ohun ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná!”—Jakọbu 3:5.
Ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà-ara ṣíṣekókó ti ọ̀rọ̀-sísọ, ṣùgbọ́n ẹ wo bí a ti ṣì í lò tó! Àwọn ènìyàn ń lo ahọ́n láti purọ́ àti láti fọ̀rọ̀-èké-banijẹ́. Pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́nà lílekoko, ba orúkọ rere wọn jẹ́, tí wọ́n sì ń lù wọ́n ní jìbìtì. Àwọn arùjàsókè ń lo ahọ́n láti dá ìyípadà àfọ̀tẹ̀ṣe sílẹ̀. Adolf Hitler lo ahọ́n tirẹ̀ láti ru orílẹ̀-èdè kan sókè fún ogun—‘iná ìgbẹ́’ nítòótọ́!
Àní àwọn wọnnì tí wọ́n ní ète-ìsúnniṣe rere pàápàá lè fa ‘iná ìgbẹ́’ kékeré kan. Ìwọ ha ti sọ ohun kan rí tí o sì dàníyàn lójú-ẹsẹ̀ pé kí o má ti sọ ọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ lóye ohun tí Jakọbu sọ nígbà tí ó sọ pé: “Ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò lè tù lójú.”—Jakọbu 3:8.
Síbẹ̀, a lè gbìyànjú láti lo ahọ́n wa fún rere. Bíi ti olórin náà, a lè fi pẹ̀lú ìpinnu gbọnyingbọnyin sọ pé: “Èmi ó maa kíyèsí ọ̀nà mi, kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀.” (Orin Dafidi 39:1) Dípò ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́nà lílekoko, a lè gbìyànjú láti gbé wọn ró. Dípò fífọ̀rọ̀-èké ba àwọn ènìyàn jẹ́, a lè sọ̀rọ̀ wọn ní rere. Dípò rírẹ́nijẹ àti títannijẹ, a lè sọ òtítọ́ kí á sì fúnni ní ìtọ́ni. Nígbà tí ọkàn-àyà rere bá jẹ́ ìsúnniṣe fún un, ahọ́n lè sọ àwọn àgbàyanu ọ̀rọ̀ afúnni nílera. Jesu lo ahọ́n rẹ̀ ní ọ̀nà yíyanilẹ́nu láti kọ́ aráyé nípa ìgbàlà.
Lóòótọ́, “ikú àti ìyè ń bẹ ní ipá ahọ́n.” (Owe 18:21) Ahọ́n rẹ ha jẹ́ aṣekúpani tàbí afúnni-ní-ìyè bí? Ó ha ń bẹ̀rẹ̀ ‘iná ìgbẹ́’ tàbí o ń pa wọ́n bí? Olórin náà gbàdúrà sí Ọlọrun pé: “Ahọ́n mi yóò sọ níti ọ̀rọ̀ rẹ: nítorí pé òdodo ni gbogbo àṣẹ rẹ.” (Orin Dafidi 119:172) Bí a bá mú ìṣarasíhùwà olórin náà dàgbà, àwa pẹ̀lú yóò lo ahọ́n wa fún rere.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Fọ́tò U.S. Forest Service