ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/1 ojú ìwé 30-31
  • Àwọn Kristian Ìjímìjí Ha Lo Orúkọ Ọlọrun Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kristian Ìjímìjí Ha Lo Orúkọ Ọlọrun Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/1 ojú ìwé 30-31

Àwọn Kristian Ìjímìjí Ha Lo Orúkọ Ọlọrun Bí?

ORÚKỌ Ọlọrun farahàn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, níbi tí àwọn kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin náà יהוה (YHWH, Tetragrammaton [Lẹ́tà Heberu mẹ́rin fún orúkọ Ọlọrun]) ti dúró fún un. Àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn dọ́gbọ́n fihàn pé ni Israeli ṣáájú ìkólọnígbèkùn sí Babiloni, ní 607 B.C.E., ìlò orúkọ náà wọ́pọ̀, ó sì farahàn lemọ́lemọ́ nínú ìwé Esra, Nehemiah, Danieli, àti Malaki tí a kọ lẹ́yìn ìkólọnígbèkùn. Ṣùgbọ́n, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí àkókò náà fún ìfarahàn Messia tí túbọ̀ ń súnmọ́tòsí, àwọn Ju tipasẹ̀ ìgbàgbọ̀ nínú ohun asán dí onílọ̀ọ́ra láti lo orúkọ náà.

Ǹjẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ha lo orúkọ Ọlọrun (tí a sábà máa ń túmọ́sì “Jehovah,” tàbí “Yahweh” ní èdè Gẹ̀ẹ́sì) bí? Ẹ̀rí sọ pé bẹ́ẹ̀ni. Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà sí Ọlọrun pé: “Ki á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.” (Matteu 6:9) Ní òpin iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, òun fúnraarẹ̀ sì gbàdúrà sí Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fifún mí láti inú ayé wá.” (Johannu 17:6) Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́kọ ti Septuagint, ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sí Griki tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lò, ní orúkọ Ọlọrun tí a kọ pẹ̀lú Tetragrammaton èdè Heberu.

Kí ni nípa ti àwọn Ìhìnrere àti ìyókù àwọn Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki (“Májẹ̀mú Titun”)? A ti fòye ronú pé níwọ̀n bí orúkọ Ọlọrun ti farahàn nínú Septuagint, yóò ti farahàn pẹ̀lú nínú àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́kọ jùlọ ti àwọn Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí—ó kérétán níbi tí a bá ti fa ọ̀rọ̀ Septuagint yọ. Nípa báyíì, orúkọ náà Jehofa farahàn ní ìgbà tí ó ju igba lọ nínú New World Translation of the Christian Greek Scriptures. Àwọn kan ti ṣe lámèyítọ́ pé kò sí ìdí fún èyí. Bí ó ti wù kí ó rí, ó jọ pé ìtìlẹ́yìn wà fún New World Translation nínú orísun kan tí kò dàbí ẹni pé ó lè pèsè ìtìlẹ́yìn: Talmud ti Babiloni.

Apá àkọ́kọ́ nínú ìwé ìsìn ti Ju yìí ni a fún ní àkọlé náà Shabbath (Ọjọ́-Ìsinmi) nínú rẹ̀ sì ni arabaríbí àkójọ àwọn òfin wa tí ń ṣàkóso ìwà ni Ọjọ́-Ìsinmi. Nínú ẹ̀ka-ìpín kan, ìjíròrò kan wà níti yálà ó jẹ́ ohun yíyẹ láti dáàbòbo àwọn ìwé-àfọwọ́kọ Bibeli kí ó máṣe jóná ní Ọjọ́-Ìsinmi, lẹ́yìn náà ni apá àyọkà ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé e yìí wá farahàn: “A sọ nínú ọ̀rọ̀-ẹsẹ̀-ìwé náà pé: Àwọn àlàfo tí a kò kọ nǹkan sí [gil·yoh·nimʹ] àti àwọn Ìwé Minim, ni a lè má dáàbòbò kúrò lọ́wọ́ iná. R. Jose sọ pé: Ní àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ ẹnìkan gbọ́dọ́ ge àwọn Orúkọ Àtọ̀runwá tí ń bẹ nínú wọn kúrò, kí ó fi wọ́n pamọ́, kí ó sì sun ìyókù níná. R. Tarfon sọ pé: Kí n gbé ọmọ mi sin bí èmi kò bá sun wọ́n nína papọ̀ pẹ̀lú àwọn Orúkọ Àtọ̀runwá náà bí ọwọ́ mi bá tẹ̀ wọ́n.”—Ìtúmọ̀ láti ọwọ́ Dókítà H. Freedman.

Ta ni àwọn mi·nimʹ jẹ́? Ọ̀rọ̀ náà túmọ̀sí “àwọn mẹ́ḿbà ẹ̀ya-ìsìn” ó sì lè tọ́kasí àwọn Sadusi tàbí àwọn ará Samaria. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Dókítà Freedman ti wí, nínú apá àyọkà-ọ̀rọ̀ yìí ó ṣeéṣe jùlọ kí ó tọ́kasí àwọn Ju tí wọ́n jẹ́ Kristian. Nítorí náà, kí ni àwọn gil·yoh·nimʹ, tí a túmọ̀sí “àwọn àlàfo tí a kò kọ nǹkan sí” gẹ́gẹ́ bí Dókítà Freedman ti sọ? Àwọn ìtúmọ̀ ṣíṣeéṣe méjì ni ó wà. Wọ́n lè jẹ́ àwọn àlàfo etí àkájọ-ìwé kan tàbí kí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àwọn àkájọ-ìwé tí a kò kọ nǹkan sí. Tàbí—nínú ìlò ọ̀rọ̀ náà bí ẹni fọ̀rọ̀ dápàárá—wọ́n lè jẹ́ ìwé tí àwọn mi·nimʹ kọ, bí ìgbà tí à bá sọ pé àwọn ìwé wọ̀nyí jẹ́ aláìníláárí bí àwọn àkájọ-ìwé tí a kò kọ nǹkan sí. Nínú àwọn ìwé atúmọ̀-èdè ìtúmọ̀ kejì yìí ni a fifúnni gẹ́gẹ́ bí “àwọn Ìhìnrere.” Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, gbólóhùn àlàyé tí ó farahàn nínú Talmud ṣáájú apá tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí kà pé: “Bí àwọn àlàfo tí a kò kọ nǹkan sí ni àwọn Ìwé Minim [gil·yoh·nimʹ] rí.”

Ní ìbámú pẹ̀lú eyí, nínú ìwé náà Who Was a Jew? láti ọwọ́ Lawrence H. Schiffman, apá náà nínú Talmud tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí ní a túmọ̀ bí ó ti tẹ̀lé e yìí: “Àwa kìí dáàbòbò àwọn Ìhìnrere àti àwọn ìwé minim (‘àwọn aládàámọ̀’) láti máṣe jóná (ní Ọjọ́-Ìsinmi). Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń sun wọn níná ní ààyè wọn, àwọn àti àwọn Tetragrammata wọn. Rabbi Yose Ha-Gelili sọ pé: Láàárín ọ̀sẹ̀, ẹnìkan níláti gé Tetragrammata wọn kúrò kí ó fi wọ́n pamọ́ kí ó sì sun èyí tí ó ṣẹ́kù. Rabbi Tarfon sọ pé: Kí n gbé àwọn ọmọ mi sin! Bí (àwọn ìwé wọ̀nyí) bá tẹ̀ mí lọ́wọ́, èmi yóò sun wọ́n papọ̀ pẹ̀lú Tetragrammata wọn.” Dókítà Schiffman ń báa lọ láti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn mi·nimʹ náà jẹ́ àwọn Ju tí wọ́n jẹ́ Kristian.

Apá yìí nínú Talmud ha ń sọ̀rọ̀ nítòótọ́ nípa àwọn Ju àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristian bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, nígbà náà ẹ̀rí lílágbára ni ó jẹ́ pé àwọn Kristian fi orúkọ Ọlọrun, Tetragrammaton náà, kún Ìhìnrere ati àwọn ìwé wọn. Lọ́nà púpọ̀ ni ó sì fi jọ́ pé Talmud náà ń jíròrò nípa àwọn Ju tí wọ́n jẹ́ Kristian níhìn-ín. Ìtìlẹ́yìn àwọn ọ̀mọ̀wé wà fún irú àwọn ojú-ìwòye náà, nínú Talmud sì nìyí ó dàbí ẹni pé àyíká-ọ̀rọ̀ náà fún un ní àfikún ẹ̀rí. Ẹ̀ka-ìpín náà tí ó tẹ̀lé ọ̀rọ̀ tí a fàyọ lókè láti inú Shabbath ròyìn ìtàn kan tí ó níí ṣe pẹ̀lú Gamalieli àti Kristian adájọ́ kan nínú èyí tí a ti sọ̀rọ̀ bá apá díẹ̀ nínú Ìwáásù Lórí Òkè.

Kìkì lẹ́yìn ìgbà náà, nígbà tí Ìsìn-Kristian apẹ̀yìndà yapa kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ rírọrùn ti Jesu, ni orúkọ Ọlọrun di èyí tí àwọn Kristian aláfẹnujẹ́ ṣíwọ́ láti máa lò tí wọ́n sì tún yọ ọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀dà ti Septuagint àti kúrò nínú àwọn Ìhìnrere àti àwọn ìwé Bibeli mìíràn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ní ọjọ́ Jesu, orúkọ Ọlọrun farahàn nínú “Septuagint”

[Credit Line]

Israel Antiquities Authority

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́