ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/15 ojú ìwé 11
  • Àwọn Kristian Inítara ti Britain

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kristian Inítara ti Britain
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—Ibi Ìyapa Ni
    Jí!—2002
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wàásù Láti Ilé Dé Ilé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìsìn Ń Wọ̀ọ̀kùn ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
    Jí!—1999
  • Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Ni Ajíhìnrere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/15 ojú ìwé 11

Àwọn Kristian Inítara ti Britain

Èyí tí kò tó ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àádọ́ta-ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ènìyàn tí ń bẹ ní Britain ni wọ́n jẹ́ Kristian onítara ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn The Economist ti wí. Ní ọjọ́ Sunday kan tí a lè wò bí àpẹẹrẹ, iye tí ó dínkù sí àádọ́ta-ọ̀kẹ́ mẹ́rin ènìyàn ní ń lọ síbi àwọn ààtò ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì. Nínú ìwọ̀nyí, kìkì 1.1 million ni wọ́n jẹ́ Anglica. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka ìgbàgbọ́ Ọlọrun kò ṣeémọ̀ tí ó wọ́pọ̀ sí, Ṣọ́ọ̀ṣì ti England ń bá ipa-iṣẹ́ rẹ̀ tí ó fìdímúlẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ìsìn Orílẹ̀-Èdè. “Fún ìgbà pípẹ́ ni Britain kò ti jẹ́ ẹgbẹ́ àwùjọ Kristian ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti tẹ́wọ́gba ìgbàgbọ́ Ọlọrun kò ṣeémọ̀, ní pàtàkì jùlọ nítorí ìyánhànhàn fún ohun tí ó ti kọjá,” ni ìwé-ìròyìn kan-náà fìdánilójú sọ. Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé àwọn òṣèlú àti ìwé-ìròyìn òde-òní béèrè fún ìmúkúrò àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì, ìyapa nínú ìsokọ́ra tí ó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-Èdè.

Walter Bagehot, olùyẹ̀wòṣàtúnṣe ìwé-ìròyìn The Economist ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún kédàárò pé: “Ayé kan tí ó jẹ́ ti ara níti gidi, tí ó fẹnujẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian, ni ayé tí ó burú jùlọ.” Ṣùgbọ́n ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., Jesu Kristi sọ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun kìí ṣe ‘apákan ayé, gẹ́gẹ́ bí òun kìí tií ṣe apákan ayé.’ (Johannu 17:16) Bí ó ti wù kí ó rí, ó rán wọn sínú ayé láti wàásù Ìjọba Ọlọrun. Bákan náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yíká-ayé ni a mọ̀-bí-ẹní-mowó fún fífi tìtara-tìtara wàásù “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.”—Iṣe 20:20.

Ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn Anglica, àwọn 126,173 Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ní Britain kéré níye. Síbẹ̀ wọ́n lo nǹkan bíi 20 wákàtí lóṣù láti lọ sí àwọn ìpàdé Kristian. Síwájú síi, ní 1992 Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan lo àfikún ìpíndọ́gba wákàtí 16 lóṣù fún pípolongo fún àwọn ẹlòmíràn ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun, àkóso náà tí yóò fìdí ayé titun òdodo kan múlẹ̀ láìpẹ́. (Matteu 24:14; 2 Peteru 3:13) Nígbà mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá tún ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ, ìwọ yóò ha fetísí ìhìn-iṣẹ́ wọn dídáyàtọ̀ kedere kí o sì ṣàwárí ohun náà tí ń sún ìtara wọn ṣiṣẹ́ bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́