Bí Igi
“EWÌ ni a ń ti ọwọ́ àwọn òmùgọ̀ bíi tèmí kọ, ṣùgbọ́n Ọlọrun nìkan ni ó lè ṣẹ̀dá igi kan.” Nípa kíkókìkí ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára ìtóye tí àwọn igi ní, akéwì Joyce Kilmer tipa báyìí bu iyìn-ọlá fún Ọlọrun fún ṣíṣẹ̀dá wọn.
Jehofa Ọlọrun ti ṣẹ̀dá àwọn igi tí wọ́n tóbi, lógo-ẹwà, tí wọ́n sì wúlò lónírúurú ọ̀nà. Àwọn igi tí kò ga àti àwọn igi gíga fíofío bákan-náà, wọ́n a máa lẹ́wà débi pé wọ́n lè kọjá àpèjúwe. Ju bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn igi a máa pèsè oúnjẹ, epo, àti ibi ààbò. Àwọn oníṣẹ́-ọnà sì ń báa lọ láti máa wá àwọn ọ̀nà titun tí wọ́n lè gbà lo igi.
Nínú Bibeli, a máa ń lo àwọn igi lọ́na àfiṣàpẹẹrẹ nígbà mìíràn láti dúró fún àwọn ìjọba, alákòóso, àti àwọn ènìyàn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. (Esekieli 31:1-18; Danieli 4:10-26) Àwọn igi ni a mẹ́nukàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ipò aláyọ̀, alálàáfíà, àti oníbìísí tí ó jẹ́ àbájáde ipò-ọba Jehofa àti ìmúpadàbọ̀sípò àwọn ènìyàn rẹ̀. (1 Kronika 16:33; Isaiah 55:12; Esekieli 34:27; 36:30) Ìwé Mímọ́ tún ṣèlérí pé ọjọ́ àwọn ènìyàn Ọlọrun yóò dàbí ti igi. (Isaiah 65:22) Èyí ní ìtumọ̀ ńlá nígbà tí a bá rántí pé àwọn igi kan ń gbé fun ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.
Olórin Bibeli kan sọ pé ẹnìkan tí dídùn inú rẹ̀ bá wà nínú àwọn òfin Ọlọrun “yóò sì dàbí igi tí a gbìn sí etí ipa odò, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀; ewé rẹ̀ kì yóò sì rẹ̀; àti ohunkóhun tí ó ṣe ni yóò máa ṣe déédéé.” Igi kan tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ tí a gbìn síbi orísun omi púpọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ rán olórin náà létí áásìkí tẹ̀mí tí ẹnìkan tí “dídùn inú rẹ̀ wà ní òfin Oluwa” ń gbádùn. (Orin Dafidi 1:1-3) Bí ìwọ bá ní inúdídùn tòótọ́ nínú òfin Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ rẹ̀, àwọn ọjọ́ rẹ lè dàbí ti igi kan. Nítòótọ́, nípa híhùwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye ti Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi, ìwọ lè fọkàn ṣìkẹ́ ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.—Johannu 17:3.