Orúkọ Ọlọrun
“Bíkòṣe pé Jehofa bá kọ́ ilé náà, àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán.” Bí àkọlé èdè Latin yìí ṣe kà nìyẹn. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni a gbékarí Orin Dafidi 127:1 nínú Bibeli, wọ́n sì ní òtítọ́ jíjinlẹ̀ nínú: Ìgbìdánwò èyíkéyìí tí kò bá ní ìbùkún Jehofa nínú yóò jásí asán níkẹyìn.
Àkọlé náà, tí déètì rẹ̀ jẹ́ 1780, ni a rí lára ilé kan ní Colombo, Sri Lanka, ó sì gba àfiyèsí nítorí pé ó ní orúkọ Ọlọrun, Jehofa, nínú. (Wo fọ́tò.) Ní àwọn ọ̀rúndún ìjímìjí, orúkọ yẹn ni a lò níbi gbogbo. A sábà máa ń kọ ọ́ sára àwọn ilé-gbígbé, ṣọ́ọ̀ṣì, àní sára àwọn owó-ẹyọ pàápàá. Àwọn míṣọ́nnárì lo orúkọ Ọlọrun nígbà tí wọ́n mú Bibeli lọ sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè, èyí tí ó fa àkọsílẹ̀ yìí ní Sri Lanka láìṣiyèméjì.
Ẹ wo bí nǹkan ti yàtọ̀ tó lónìí! Díẹ̀ nínú àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian ni wọ́n bìkítà nípa orúkọ Ọlọrun. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tilẹ̀ ṣe lámèyítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún títẹnumọ́ ọn. Èéṣe? Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti wí, nítorí pé a kò mọ bí a ṣe ń pè é lédè Heberu ní pàtó. Ṣùgbọ́n ẹni mélòó ni o mọ bí a ti ń pe orúkọ Jesu lédè Heberu ní ìpilẹ̀ṣẹ̀? Síbẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni a ń lò jákèjádò àgbáyé tí a sì bọ̀wọ̀ fún.
Orúkọ Ọlọrun ṣe pàtàkì fún Jesu gan-an. O kọ́ wa láti gbàdúrà pé: “Kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.” (Matteu 6:9) Ní kété ṣáájú ikú rẹ̀, ó wí fún Ọlọrun pé: “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fifún mi láti inú ayé wá.” (Johannu 17:6) Àwọn Kristian tòótọ́ jẹ́ ọmọlẹ́yìn atọpasẹ̀ Jesu. Àwọn pẹ̀lú kò ha níláti ‘sọ orúkọ Ọlọrun di mímọ̀ bí’? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jehofa sì ń bùkún “ilé” wọn lọ́nà dídọ́ṣọ̀. Fún wọn psalmu náà jẹ́ òtítọ́ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn náà tí Ọlọrun wọn jẹ́ Jehofa!”—Orin Dafidi 144:15, NW.