Wọ́n Ha Lè Ṣàǹfààní fún Ọ Bí?
ÌWÉ-ÌRÒYÌN tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ yìí ni a wéwèé rẹ̀ láti jẹ́ orísun ìṣírí, ní ríránnilétí àwọn ìlànà Bibeli fún fífẹsẹ̀ ìdílé múlẹ̀ àti dídi ìwàtítọ́ ẹni mú. Ó fihàn pé àwọn àkókò oníjàngbọ̀n ti òde-ìwòyí ni a sọtẹ́lẹ̀ nínú Bibeli, ó sì tẹnumọ́ ojútùú náà—àkóso Ìjọba Ọlọrun. Ìwọ ha lè jàǹfààní láti inú Ilé-Ìṣọ́nà àti láti inú Jí!, tí ó jẹ́ ìwé-ìròyìn tí ó ṣìkejì rẹ̀ bí?
Láti Philippines ni obìnrin kan tí ńjẹ́ Vilma ti kọ̀wé pé: “Bí ọ̀rọ̀ èyíkéyìí bá wà láti fi ṣàpèjúwe àwọn ìtẹ̀jáde yín, mo rò pé èmi yóò yan ‘àgbàyanu.’ Mo rí Jí! àti Ilé-Ìṣọ́nà yín fún ìgbà àkọ́kọ́ mo sì kà á nígbà tí mo wà nínú ọkọ̀ bọ́ọ̀sì padà sílé láti Manila. Mó sába máa ń mú àwọn ìwé-ìròyìn dání nígbà tí mo bá ń rìnrìn-àjò, ṣùgbọ́n ní àkókò yìí èmi kò mú ọ̀kankan lọ́wọ́.
“Ọkùnrin kan tí ó ti tóójúbọ́ tí ó ní àwọn ìtẹ̀jáde yín lọ́wọ́ ni ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi lákòókò ìrìn-àjò ráńpẹ́ náà. Lẹ́yìn tí ó ka Jí! tán, ó mú ìwé-ìròyìn mìíràn jáde, Ilé-Ìṣọ́nà, mo lo àǹfààní tí ó ṣí sílẹ̀ náà láti yá Jí! lọ́wọ́ rẹ̀. Láti sọ òtítọ́, mo gbádùn kíka àwọn ìwé-ìròyìn náà níti gidi nítorí pé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n gbádùnmọ́ni, bọ́sákòókò, tí wọ́n sì ń gbéniró.”
Obìnrin náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo fẹ́ láti gba àwọn ìwé-ìròyìn yín. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí ń mọ bí mo ṣe lè rí wọn gbà.” Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Philippines láyọ̀ láti dáhùn sí ìbéèrè náà nípa fífi orúkọ obìnrin yìí kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́rùráńṣẹ́ wọn.