Bí Ápù Wúrà
ÁPÙ—ẹ wo bí wọn ti dùn-ún wò tí wọ́n sì dùn lẹ́nu tó! Bibeli lo èso adùnyùngbà yìí nínú ọ̀rọ̀ àsọfiwéra kan tí ń múnironújinlẹ̀ nígbà tí ó sọ pé: “Bí àwọn ápù wúrà nínú àwọn ohun-gbígbẹ́ fàdákà ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò yíyẹ fún un.” (Owe 25:11, NW) Kí ni gbólóhùn yìí túmọ̀ sí?
“Àwọn ápù wúrà nínú àwọn ohun-gbígbẹ́ fàdákà” lè tọ́ka sí ohun-gbígbẹ́, irú bíi ọpọ́n fàdákà kan tí a fín nínú èyí tí àwọn èso wúrà wà. Níwọ̀n bí àwọn ẹsẹ tí ó ṣáájú nínú orí yìí ti mẹ́nukan títọ ọba kan lọ, ẹsẹ yìí lè tọ́ka sí àwọn ẹ̀bùn tí a fifún olùṣàkóso kan—àwọn ohun-ọ̀ṣọ́ wúrà tí ìrísí wọn dàbí ti àwọn ápù tí a kò sínú àwọn ọpọ́n fàdákà. (Owe 25:6, 7) Nítòótọ́, ẹ wo bí ó ti lẹ́wà lọ́nà tí ó wọnilọ́kàn tó!
Ẹwà bí irú èyí wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ, wíwuyì, bíbọ́sákòókò tí a kọsílẹ̀ tàbí sọ lọ́rọ̀. Wọ́n ń gbádùnmọ́ni, wọ́n ń fúnniníṣìírí, wọ́n sì ń ṣàǹfààní ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Pàápàá ní pàtàkì ni àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí àtọ̀runwá tí ń bẹ nínú Bibeli lẹ́wà bí “àwọn ápù wúrà nínú àwọn ohun-gbígbẹ́ fàdákà.”
Gẹ́gẹ́ bí Ọba Solomoni tí ṣàpèjúwe nínú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n rẹ̀ ní Owe 25:11, ó “wá ọ̀nà àti rí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti kíkọ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ yíyẹrẹ́gí.” (Oniwasu 12:10, NW; Owe 25:1) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Kristian aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní.” (2 Timoteu 3:16, NW) Bẹ́ẹ̀ni, Bibeli ní àwọn ìmọ̀ràn, àsọtẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ àpèjúwe, àti àwọn òtítọ́ ṣíṣàǹfààní tí wọ́n ní ìdányanran àti ẹwà tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi tayọ iṣẹ́ àwọn oníṣẹ́-ọnà tí wọ́n jáfáfá jùlọ lọ́nà gíga. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jèrè ọgbọ́n láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, ń jèrè ohun-ìní tí kò ṣeédíyelé, ó sì lè fọkànṣìkẹ́ ìrètí ìyè ayérayé.—Owe 4:7-9; Johannu 17:3.