Ta Ni Ó Gbàgbọ́ Nínú Àwọn Ẹ̀mí Búburú?
ÌWỌ ha gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀mí àìrí lè lo agbára ìdarí lórí ìgbésí-ayé rẹ bí? Ọ̀pọ̀ yóò fi ìtẹnumọ́ dáhùn pé bẹ́ẹ̀kọ́. Nígbà tí wọ́n jẹ́wọ́ wíwà Ọlọrun, wọ́n fi èròǹgbà wíwà àwọn oníṣẹ́ ibi tí wọ́n ju ẹ̀dá ènìyàn lọ rẹ́rìn-ín-ẹlẹ́yà.
Àìnígbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀mí wà tí ó tànkálẹ̀ nínú àwọn ẹ̀mí ní àwọn apá Ìwọ̀-Oòrùn ayé lápákan jẹ́ nítorí agbára ìdarí Kristẹndọm, èyí tí ó ti kọ́ni fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún pé ilẹ̀-ayé jẹ́ àárín gbùngbùn àgbáálá-ayé, tí ó wà láàárín ọ̀run àti ọ̀run-àpáàdì kan tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ yìí ti fi kọ́ni, àwọn angẹli ń gbádùn ayọ̀ pípé pérépéré ní ọ̀run nígbà tí àwọn ẹ̀mí-èṣù ń ṣàbójútó àwọn alámọ̀rí ọ̀run-àpáàdì.
Bí àwọn àwárí nínú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ti ń mú kí àwọn ènìyàn kọ àwọn èrò tí kò tọ̀nà nípa ìgbékalẹ̀ àgbáálá-ayé sílẹ̀, ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí di èyí tí kò bódemu mọ́. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ náà The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Nínú àbárèbábọ̀ àtúnṣe-èrò-ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti Copernicus ṣe ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún (tí a gbékarí àwọn àbá-èrò-orí onímọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmà ọmọ-ilẹ̀ Poland náà Copernicus), nínú èyí tí . . . a kò ti rí Ilẹ̀-Ayé gẹ́gẹ́ bí àárín-gbùngbùn àgbáálá-ayé mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, tí a wulẹ̀ rí i gẹ́gẹ́ bíi planẹẹti kan lára ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn planẹẹti tí wọ́n faramọ́ oòrùn tí ó jẹ́ apá kékeré bíńtín nínú ìṣùpọ̀ àwọn ìràwọ̀ nínú àgbáyé kan tí ó dàbí ẹni pé kò lópin—kò tún dàbí ẹni pé èròǹgbà náà nípa àwọn angẹli àti àwọn ẹ̀mí-èṣù jẹ́ ohun yíyẹ.”
Nígbà tí ọ̀pọ̀ kò gbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀mí búburú, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ń bẹ tí wọ́n gbàgbọ́ nínú wọn. Àwọn angẹli tí wọ́n ti ṣẹ̀ kó ipa pàtàkì nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìsìn, ní ìgbà tí ó ti kọjá àti nísinsìnyí. Yàtọ̀ sí ipa-iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí olùba ipò tẹ̀mí jẹ́, àwọn angẹli búburú wọ̀nyí ni a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà àwọn ìjábá, bí ogun, ìyàn, àti ìsẹ̀lẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n tún jẹ́ olùmú àìsàn, ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ, àti ikú pọ̀ síi.
Satani Eṣu, ògúnnágbòǹgbò ẹ̀mí búburú nínú ìsìn Kristian àti ti àwọn Ju, ni àwọn Musulumi pè ní Àbìlíì. Nínú ìsìn Zoroastrian ti àwọn Persia ìgbàanì, ó farahàn gẹ́gẹ́ bíi Angra Mainyu. Nínú ìsìn Onímọ̀-Awo, èyí tí ó gbilẹ̀ ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta C.E., a rí i gẹ́gẹ́ bíi Demiurge, èdè-ìsọ̀rọ̀ náà tí wọ́n fifún ọlọrun rírẹlẹ̀ kan tí ó jẹ́ òjòwú ẹni náà tí apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú aráyé ń jọ́sìn láìmọ̀.
Àwọn ẹ̀mí búburú tí ipò wọn kéré farahàn ketekete nínú àwọn ìsìn Ìlà-Oòrùn. Àwọn Hindu gbàgbọ́ pé àwọn asura (àwọn ẹ̀mí-èṣù) ń ṣòdìsí àwọn deva (àwọn ọlọrun). Àwọn tí a bẹ̀rù jùlọ lára àwọn asura ni àwọn rakshasa, àwọn amúnigbọ̀nrìrì ẹ̀dá tí wọ́n ń pààrà àwọn itẹ́-òkú.
Àwọn onísìn Búdà ronú pé àwọn ẹ̀mí-èṣù jẹ́ agbo-àwùjọ kan tí ó ní àwọn ìwà-ànímọ́ tí ń ṣèdíwọ́ fún ènìyàn láti máṣe nírìírí Nirvana, àkúrun ìfẹ́-ọkàn. Olórí olùdẹwò lára wọn ni Mara, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta Rati (Ìfẹ́-Ọkàn), Raga (Adùn), àti Tanha (Àìní-Ìsinmi).
Àwọn ọmọ-ilẹ̀ China tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn ń lo àwọn iná ayẹyẹ, ètùfù, àti àwọn iná abùyẹ̀rì láti dáàbòbò wọ́n lọ́wọ́ kuei, tàbí àwọn ẹ̀mí-èṣù ti ìṣẹ̀dá. Ìsìn àwọn ọmọ-ilẹ̀ Japan tún gbàgbọ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀mí-èṣù ní ń bẹ, títíkan tengu adẹ́rùbani, àwọn ẹ̀mí tí ń gun àwọn ènìyàn títí tí àlùfáà kan yóò fi lé wọn jáde.
Láàárín àwọn ìsìn Asia, Africa, Oceania, àti ti àwọn ilẹ̀ America tí ó jẹ́ ti àwọn púrúǹtù, wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí lè rannilọ́wọ́ tàbí panilára ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àyíká-ipò àti ipò-ọkàn tí wọ́n bá wà. Àwọn ènìyàn ń jọ́sìn àwọn ẹ̀mí wọ̀nyí láti taari àjálù-ibi dànù kí wọ́n sì rí ojúrere gbà.
Ní àfikún sí gbogbo èyí ni ọkàn-ìfẹ́ tí ó tànkálẹ̀ nínú idán àti ìbẹ́mìílò, ó sì ṣe kedere pé ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀mí búburú ní ìtàn gígùn tí ó sì gbalẹ̀ káàkiri. Ṣùgbọ́n ó ha lọ́gbọ́n-nínú láti gbàgbọ́ pé irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ wà bí? Bibeli sọ pé wọ́n wà. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà, èéṣe tí Ọlọrun fi fàyègbà wọ́n láti nípalórí ènìyàn sí ìfarapa rẹ̀?