“Ẹ Jẹ́ Kí A Ka Díẹ̀ Si Kí A Tó Pẹ̀gàn”
ÌYẸN ni ohun tí ẹnìkan láti New Zealand sọ nípa Ilé-Ìṣọ́nà, ìwé ìròyìn náà tí ìwọ ń kà. Onítọ̀hùn kọ̀wé nípa ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó níí ṣe pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ti Ọlọrun tí a ṣàpèjúwe nínú Esekieli orí 1, pé:
“Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin, tàbí kérúbù wọ̀nyí, ní ìyẹ́ mẹ́rin, àti ojú mẹ́rin. Wọ́n ní ojú kìnnìún, tí ó dúró fún ìdájọ́-òdodo Jehofa; ojú màlúù, tí ń ṣàpẹẹrẹ agbára Ọlọrun; ojú idì, tí ó dúró fún ọgbọ́n; àti ojú ènìyàn, tí ń tọ́ka sí ìfẹ́ Jehofa.
“Lẹ́yìn kíka èyí lákàtúnkà léraléra, mo nímọ̀lára ayọ̀ jíjinlẹ̀ nínú ọkàn-àyà mi. Omijé ayọ̀ wá sí ojú mi. Èrò tí ó wá sọ́kàn mi lẹ́sẹ̀kẹṣẹ̀ ni, ‘Ìwọ ti níláti lẹ́wà tí ó sì níláti wuni tó Jehofa!’ Araami mú mi kún fún ìyàlẹ́nu nípa àwọn ìmọ̀lára titun tí mo ní fún Jehofa Ọlọrun yìí ẹni tí mo ti kẹ́gàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, èmi ẹni ayé. Mo sọ pé ‘ẹ ṣeun’ fún ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jehofa, àti fún ọ̀pọ̀ bí tèmi, mo sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a ka díẹ̀ síi kí a tó pẹ̀gàn.’”