ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/15 ojú ìwé 32
  • “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Dáàbòbò Mí!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Dáàbòbò Mí!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/15 ojú ìwé 32

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Dáàbòbò Mí!”

NÍ ÀWỌN ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ti fi araawọn hàn pé wọ́n jásí “òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (2 Timoteu 3:​1, 3) Isaac, òjíṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni kan ní ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa, rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́. Ó sọ pé:

“Ní January 1992, mo ń rìnrìn-àjò lọ ní ojú-ọ̀nà gígùn kan tí ó dá nínú ọkọ̀ taksi akérò pẹ̀lú àwọn èrò ọkọ̀ márùn-⁠ún mìíràn. Mó bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jókòó tì mí, ó sì fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́gba ìwé-pẹlẹbẹ kan tí ń sọ̀rọ̀ nípa Bibeli lọ́wọ́ mi.

“Lójijì, ní nǹkan bí agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ titun kan tí kò ní nọ́ḿbà kọjá síwájú wa lójijì, ọkọ̀ wa sì dúró lójijì pẹ̀lú ariwo púpọ̀. Àwọn gìrìpá ọkùnrin mẹ́ta, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú ìbọn rìfọ́fà lọ́wọ́, bẹ́ jáde láti inú ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ kejì náà wọ́n sì fa ilẹ̀kùn wa ṣí. Ọ̀kan nínú wọn bú jáde pé, ‘Gbogbo yín, ẹ jáde.’

“Ọkùnrin kejì já àpò ìwé mi gbà. Nígbà tí ó rí i pé kìkì àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni ó wà nínu rẹ̀, ó ju báàgì náà dànù. Pẹ̀lú ìbọn tí ó nà sí mi, ó béèrè pé, ‘Kíló tún kù lọ́wọ́ ẹ?’ Mo yára fún un ni owó tí ó wà nínú àpamọ́wọ́ mi. Ó béèrè pé, ‘Ṣe gbogbo rẹ̀ nìyẹn?’ Mo sọ fún un pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni mi àti pé àwọn Ẹlẹ́rìí kìí purọ́. Ó já àpamọ́wọ́ náà gbà lọ́wọ́ mi, ó rí káàdì ìdánimọ̀ Watch Tower mi tí ó sì sọ pé, ‘Ó dára, Watchtower. Dúró síbí.’

“Lẹ́yìn náà, ó yíjúsí obìnrin tí mo ti bá ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nínú taksi náà. Ó yára bọ́ ṣéènì ọrùn rẹ̀ kúrò ó sì fún un ní owó tí ń bẹ nínú pọ́ọ̀sì rẹ̀. Nígbà tí dánàdánà náà ṣàkíyèsí ìwé-pẹlẹbẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ tí ń gbọ̀npẹ̀pẹ̀, ó tànmọ́ọ̀ pé ọ̀kan náà ni wá, nítorí náà ó sọ fún un pé kí ó dúró tì mí.

“Bí èyí ti ń lọ lọ́wọ́, àwọn adigunjalè yòókù ń gbéjàko àwọn tí a jọ ń rìnrìn-àjò lọ́nà rírorò. Wọ́n lu awakọ̀ náà àti ọkùnrin kejì tí a jọ ń rìnrìn-àjò wọ́n sì gba ohun tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Olè kan já ṣéènì ọrùn obìnrin kejì gbà. Nígbà tí ó jampata, wọn fìwà òǹrorò gbá ìdí ìbọn mọ́ ọn lórí àti ní àyà títí tí ó fi kú. Wọ́n wọ́ obìnrin kẹta jáde láti inú ọkọ̀ wọ́n sì yìnbọn fún un ní àyà. Ó ṣeniláàánú pé òun pẹ̀lú kú. Èmi nìkan àti obìnrin náà tí ó wà pẹ̀lú mi ni wọ́n kò ṣe ìpalára kankan fún.

“Lẹ́yìn náà nígbà tí onímọ́tò mìíràn tí ń kọjá lọ gbé wa, obìnrin tí àyà rẹ̀ já náà ń sọ ní àsọtúnsọ pé, ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dáàbòbò mí!’”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́